Jaiyeola Bisiriyu, Ekiti
Dokita Kayode Fayemi ti jawe olubori nibi idibo gomina to waye lojo Satide ana nipinle Ekiti.
Ibo 197,459 la gbo pe Kayode Fayemi fi la akegbe e, Ojogbon Kolapo Olusola ti egbe oselu PDP pelu ibo 178,114 gege bi eni to ka ibo naa, Ojogbon Idowu Olayinka se kede sita.
A gbo pe ijoba ibile mejila ninu ijoba ibile merindinlogun to wa nipinle Ekiti ni Fayemi ti jawe olubori, nigba ti Kolapo jawe olubori ni ti e nijoba ibile merin pere.
Lara awon asiri to tu s'AWIKONKO lowo ni pe bi awon omo egbe oselu APC se n fowo ra ibo, bee lawon omo egbe oselu PDP naa fowo ra ibo, sugbon ta a gbo pe owo ti APC fi ra ibo po ju ti PDP.
AWIKONKO gbo pe gbogbo gomina ile Yoruba, to fi mo awon agbaagba egbe oselu APC lorileede Naijiria ni won lo sipinle Ekiti nitori idibo gomina naa, lati loo satileyin fun Fayemi.
Opo awon oludibo la gbo pe won jade sita lati dibo fun eni to wun won lokan, sugbon nigba toro naa di ti olowo de, se lawon eeyan bere sii yin okan won pada lati dibo fawon to ba fun won lowo.
A ti e tun gbo pe se lawon alakoso ti won yan sawon agbegbe ti won ti dibo lo n bawon eeyan nile won pe ki won wa a dibo nitori pe owo wa nile ti won yoo gba bi won ba le fi dibo.
Won ni wahala fe e be sile lawon ile idibo kan laarin awon asoju egbe oselu nibe nigba ti won bere sii fi owo parowa fawon oludibo lati dibo fun egbe oselu won.
Nibi ti won ni awon asoju egbe oselu PDP ti ko fawon oludibo ni egberun meta naira lati dibo fun won, ni awon asoju egbe oselu APC naa ti n fawon oludibo ni egberun marun naira lati dibo fun egbe oselu won.
AWIKONKO gbo pe awon to ni Kaadi idibo alalope PVC ni won n gba egberun marun naira lesekese ki won too dibo, sugbon ti baba agba kan ta a foruko bo lasiri to soro so pe oun ko gba owo naa lowo won nigba ti won fi lo oun.
Ohun ta a tun gbo ni pe, ni agbegbe Ayangbaju, egberun meji naira ni won lawon asoju egbe oselu n fawon ti ko ni kaadi idibo alalope lati dibo pelu ifowosowopo pelu awon osise eleto idibo ti won wa nibe.
Okan alara awon osise eleto idibo to n mojuto bo se n lo nipinle Ekiti (Operations and Logistics), Arabinrin Aminat Zakari ti fiwe esun kan Gomina Fayose pe ko tete ko iwe ebe laarin wakati mejidinlaadota (48hours) fun esun ibaniloruko je to fi kan oun.
Lojo keji osu yi ni Gomina Fayose pariwo sita pe obinrin naa fe e gbabodi lati sise fun Kayode Fayemi ti egbe oselu APC, ko ba a le jawe olubori gege bi gomina ipinle naa leyin idibo.
Obinrin naa ni gbogbo iwe iroyin loun ti fe e ri iwe ebe aforiji naa ko too pe asiko toun fun, bi ko ba fe e fi ewon se ifa je.