IDI TI OBASANJO FI LO SIPADE EGBE OSELU PDP L'ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 10, 2018

IDI TI OBASANJO FI LO SIPADE EGBE OSELU PDP L'ABEOKUTA

Bo tile je pe titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo ni oro naa si n je kayeefi fawon omo egbe oselu PDP, paapaa awon omo orileede Naijiria to gbo nipa bi Oloye Olusegun Obasanjo to je Aare orileede yi labe egbe oselu naa leemeji otooto sugbon to ti fa kaadi egbe naa ya tun se pada loo sibi ipade ti won se l'Abeokuta lojo Monde ana to koja yi.


Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, adije sipo gomina ninu eto idibo odun 2019 to n bo lona labe egbe oselu naa, Onarebu Oladipupo Adebutu lo loo sepade papo pelu awon omo egbe naa ni aarin gbungbun ipinle Ogun, iyen Ogun Central.

Inu ogba ile ikawe Oloye Obasanjo ni ipade naa ti waye, bo tile je pe won ti koko loo sabewo si Alake tile Egba, Oba Michael Adedotun Aremu Gbadebo ni aafin e to wa ni Ake.

AWIKONKO gbo pe ko pe ti Onarebu Adebutu atawon ti won jo loo ki Alake ni aafin pada de gbagede ile ikawe ti Obasanjo, iyen Obasanjo Presidential Library, tonikaluku won si n soro oselu lowo ni won so pe Oloye Obasanjo n koja lo, to si ya sibe.

Iyalenu lo je fun opo awon to ri Baba Obasanjo, ti won si la enu won si, ti esinsin fe e le maa ko si. Lesekese ni won ti bere sii dobale kii, toun naa si bawon rerin.


Ko pe la gbo pe Ebora Owu gba ero gbohun-gbohun, iyen microphone lati soro, bo tile je pe ko tii seni to fe e mo nnkan to fe e so.

Nigba ti Obasanjo maa soro, ohun to so ni pe "Mo ki gbogbo yin o, eku eto ilu. Mo n koja lo ni mo ri awon ero to po. Mo si ni ki n ya woo pe boya ere ni won n se tabi ere ko.

"To ba je pe ere ni, ti ko ba si je ere ni, a maa mo to ba ya. Nitori naa, mo kii yin pe e ku ipade o."

PÍN-IN KÁÀKIRI