IDIBO 2019: AWON OLOLUFE SEGUN GBELEYI BERE IPOLONGO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 4, 2018

IDIBO 2019: AWON OLOLUFE SEGUN GBELEYI BERE IPOLONGO

Bi omo eni ba dara, o ye ka wi, bi omo eni ba si ku die kaato, ko ye ka fi pa mo, eyi gan an lo lo nibamu pelu bi awon ololufe gbajumo oloselu nni, Onarebu Olusegun Bolanle Gbeleyi se bere ipolongo idibo fun un.


Onarebu Segun Gbeleyi to je oludamonran pataki fun Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun lori oro ina (consultant to Gov. Amosun on Power) la gbo pe o fe e jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin (House of Representative) niluu Abuja lati ekun Ogun West ninu idibo odun 2019 to n bo lona yii labe egbe oselu APC.


Lose to koja si ose yi, la gbo pe awon ololufe okunrin naa loo se posita ipolongo, iyen Billboard nla meta, ti won si loo rii sawon agbegbe bii Ilaro, Ota ati Ayetoro loju ona Imeko/Afon fawon araalu lati rii.


Be o ba gbagbe, Onarebu Segun Gbeleyi ti figba kan ri je igbakeji olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, iyen lodun 1999 si 2003, to si tun loo soju ipinle Ogun nibi ipade awon asofin lagbaye.


Onarebu Gbeleyi ti sagbateru awon abadofin repete, to si je pe pupo ninu awon abadofin naa ni won ti so di ofin. Opo awon to mo okunrin oniwa tutu yi ni won ko le gbagbe awon ipa to ko nigba to fi wa nipo, paapaa lasiko yi.

Eyi gan an ni won loo je kawon araalu to gba ti e woo pe kawon tete bere ipolongo idibo naa fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI