IJOBA KO FUN EGBE FIBAN LOWO OSU O - OMILANI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 16, 2018

IJOBA KO FUN EGBE FIBAN LOWO OSU O - OMILANI PARIWO SITA

Alaga egbe sorosoro lorileede Naijiria, Freelance and Independent Broadcasters' Association of Nigeria, FIBAN, eka tipinle Ogun, Komureedi Samuel Olufemi Iyanda Omilani ti pariwo sita pe egbe awon kii se egbe oloselu, tawon ko si ledi apo papo mo egbe oselu kankan lorileede yii.


Komureedi Omilani lo soro yi losan onii lasiko to n b'AWIKONKO soro nile egbe won to wa ladugbo Isabo niluu Abeokuta, iyen nibi ere idije ti idaraya, eyi ti won se lati fi saami ayeye odun kan tawon oloye egbe naa gbajoba.

O lawon ko darapo mo egbe oselu tawon ko si sise fun oloselu kankan, nise lawon da duro loto, tawon ko si gba owo osu lowo ijoba nitori pe awon kii se osise ijoba.

Ninu oro e, o so pe "Ko si otito ninu pe egbe wa ti di egbe oselu, awa ko darapo mo oloselu. Oto ni egbe FIBAN rin, a da duro ni, awa ko gba owo osu lowo ijoba kankan, a o si gba owo osu lowo enikeni. Ologun da duro ni wa, sugbon a ko ba ijoba kankan ja, bee naa la o si bawon to n fe de ipo ijoba naa se ota. A o wonu ijoba ju bo se ye lo, bee naa ni ajosepo wa ko baje, ti ko si nii baje lailai."

Bakan naa o so pe awon ni ajosepo to dan monran pelu ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun, nitori pe opolopo awon alabojuto, iyen awon Komisana ni won n fowosowopo pelu won, ti won si n gbaruku ti won, paapaa ni ti eto iranti oloogbe Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye to waye lai pe yii.

O lawon si n gbiyanju lati ri Gomina Amosun funra e latari awon oro asoyepo tawon fe e ba a so, toun si mo pe lai pe, aaye naa yoo si sile fawon.

Siwaju sii nigba yo n soro lori idi ti won fi gbe eto ere idaraya naa kale, Omilani je ko di mimo pe lati tubo je ki ife ati alaafia joba ninu egbe, paapaa lati je kawon omo egbe naa tubo da ara won mon daadaa.

Komureedi Omilani wa rawo ebe sawon omo egbe naa, paapaa awon ti won yapa kuro ninu egbe pe ki won fowo wonu, ki won si pada lati wa maa fowosowopo pelu won ninu egbe nitori pe agbajowo nikan lo le gbe eru sori, nitori naa ki won gbagbe awon nnkan to ti sele seyin.

Saaju akoko yi ni alaga egbe SWAN, Alaaji Akintunde ati alaga egbe asojukoroyin, Komureedi Adewumi gbawon omo egbe naa lamonran pe ki won gbiyanju lati tubo je ki ajosepo to dan monran wa laarin won pelu awon egbe min in to nii se pelu iroyin tabi sorosoro, ki won si pe won mora lati bawon kopa nibi awon ere idije ti won ba fe e se.

Yato si Aare egbe naa, Komureedi Desmond Abiodun Nwachukwu, lara awon to tun wa nibi eto naa ni Komureedi Wole Sokunbi to je alaga egbe akoroyin nipinle Ogun; Komureedi Wale Adewumi to je alaga egbe asojukoroyin (Correspondent Chapel); alaga egbe akoroyin ere idaraya, Sports Writers Association of Nigeria, SWAN, Alaaji Akeem Akintunde.

Awon min in ni: Oloye Monsuru Ijayegbemi, Alaaji Asamu Akinrinde, Ogbeni Gbenga Sodeke to fi mo Ogbeni Gbenga Oladipupo to je akoroyin fun ileese Alariya Oodua.

Lara awon ere idaraya to waye ni: Ayo Olopon, Kaadi (What), Dirafti, Ludo atawon kin in.

PÍN-IN KÁÀKIRI