KI LO SE OMO YORUBA PELU KEMI ADEOSUN? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 15, 2018

KI LO SE OMO YORUBA PELU KEMI ADEOSUN?

Eku dede asiko yii, gbogbo eyin ololufe iwe Iroyin Awikonko ati gbogbo omo Yoruba patapata. Awon agba bo, won ni "Agba kii wa l'oja ki ori omo tuntun wo", a bi oro yi ko ri be mo ni? Bee si ni won tun so pe "Eyi o to nkan beeni sokoto awe ku penpe".


Ni iran ni leti oro "Igi eyi ko dara, e yoo s'igbo; tohun ko dara, e yoo so'nu si’gbo; igi wo gan an la o wa fi dana?".

Gbogbo asamo awe wonyii ko se leyin ohun to n sele lagbo oselu orileede Naijiria. Ibeere naa ni yii, nibo ni wahala Yoruba ti bere, kinni isoro awa Yoruba gan an? Atipe awon Ojogbon kan ti le so pe isoro Yoruba ko wa lati odo eya miiran wa, bi ko se pe owo ara wa naa la fi n se ara wa.

Etanje ko ye wa, ija, ote ati tenbelekun ni won fi te opolopo ile Yoruba, bee si ni Yoruba padanu ile Yoruba miiran gege bi ilu Ilorin si owo awon Fulani nipase ote, tenbelekun ati dukuu eyi ti ko fi igba kan duro.

E je ka pada si ohun to sele ni lai pe yii, awon agbalagba gbogbo lo mo pe wahala Awolowo to wa nile lo si n fa ote saarin ilu. Bee si ni isoro to do’juko Ogagun Oladipupo Diya ko seyin omo Yoruba, ati pe iku to pa Oloogbe Basorun Moshood Olawale Abiola ko sai ni owo Yoruba ninu. Ta a ni ota Baba Iyabo?, se bi omo Oduduwa yi kan naa ni.

Awon ara eya miiran yoo da ina ija sile fun wa lati doju oro kan ara wa, bee si ni Yoruba ko nironu pe ati eerun ati ejo ni agbe n sa fun.

Wahala miiran lo tun n rugbo bo lagbo oselu orileede Naijiria bayii, abi kinni ti isoro eyii to doju ko Kemi Adeosun? Meloo ni omo Yoruba eyii to wa l'oke lagbo oselu? Sugbon iwonba awon to tun wa nibe, sebi se lo ye ki omo Oduduwa gbaruku tii, ti won kun un lowo ni, di po bee orin "maa bo nile, pada siluu e" ni won n ko fun awon to wa nibe.

Awa la ni asa ati isese wa, e ma se je ka gbagbe isese wa. Eyin agba ile Yoruba, eyin egbe Afenifere ni bo le wa?, e ma se je ki a fi ti egbe oselu se, e ranti okunrin oni’rungbon kan to k'ogun ja wa lojosi, eni to tun sa lo si orileede Ivory Coast fun opolopo odun, se bi ni gba ti o de se ni awon iran re gba t'owo-t'ese, ti won si tun fi opolopo oye da a l'ola, kinni ka ti wa a pe ti Yoruba?

Asiko le yii to ye ki a tun ile wa see, ka si bo asiri awon eni wa to ba wa ni ori oke, e ranti pe ti Olukemi Adeosun ba subu, gbogbo Yoruba ni osubu.

Gbogbo eyin egbe agba Yoruba, Aare Ona Kakanfo, Otunba Gani Adams; eyin Omowe, eyin amofin ati eyin ti Olodumare fi si ipo agbara, e je ka ranti ohun to sele si ilu Ilorin nipase alejo oran yii ti Are Afonja gba. E ranti bi omo alade se di omo oni lawaani ni’lu Ilorin.

Iru alejo bayii ni ijoba apapo fe e fi tipa-tipa gbe le wa lori yii oo, abi ewo ni ti awon Fulani adaranje eyi ti ijoba fe gba ile wa fun ni tipatipa. E ranti pe ati ti ese boodo ooni he ponkan, gbogbo wa la ti ri itu ti awon Fulani adaranje fi awon to gba won ni alejo, oro itan ko ni eleyi, e je ki gbogbo awon agbaagba ile Yoruba dide lai da ilu kan si, ka le ja ijagbara lowo ijoba to fe fi Fulani je gaba le wa lori, e je ka ranti pe ti a ba so pe ko kan wa, ojo n bo ti yoo wa kan awon aromodomo wa, nitori pe iyan ogun odun a ma gbona feli-feli.

Amoran ni oro atokun jo ni ose yii, e ranti pe iwe iroyin Awikonko kii se ti egbe oselu kankan, beeni ko si gbe leyin oloselu tabi egbe oselu.

E pade emi omo yin, ololufe yin labala yii lose to n bo pelu itan Afonja ilu Ilorin ati bi awon Fulani se di alejo oran si Afonja lorun. Eku afoju s'ona.

Tayo Adio
0810-508-8418

PÍN-IN KÁÀKIRI