KO SI ENI TO LE YO MI KURO NIPO ALAGA EGBE OSELU PDP IPINLE OGUN – BAYO DAYO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 30, 2018

KO SI ENI TO LE YO MI KURO NIPO ALAGA EGBE OSELU PDP IPINLE OGUN – BAYO DAYO


Alaga egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP nipinle Ogun, Enjinia Adebayo Dayo ti soro, o ni ko seni to le yo oun gege bi alaga egbe oselu naa nipinle Ogun, nitori pe oun gan an ni ojulowo alaga tawon omo egbe dibo yan, to si tun ni ase kootu ninu. O so pe ayafi toun ba feyinti gege bi alaga egbe naa, lodun 2020 si ni. Enjinia Bayo Dayo lo soro yi lojo Tusde ose to koja lasiko to n b’AWIKONKO soro ninu ofiisi ile egbe naa to wa ni Oke-Mosan niluu Abeokuta. E ka bi iforowero naa se lo sii.

Bayo Dayo
AWIKONKO: Egbe oselu PDP lapapo niluu Abuja kede site lai pe yi pe awon ti yo yin kuro ninu egbe, se looto ni, ati pe ki le ri sii. Bawo loro naa se je?
BAYO DAYO: E seun pupo, nnkan to wa nile ni pe ose to koja yi ni mo lo siluu Abuja lati loo pin iwe idajo tile ejo kotemilorun (Court of Appeal) fun wa. Gbogbo awon osise egbe ti won n sise patapata ni mo fun niwe idajo naa. Mo ro pe ibi ti oro naa tan si niyen, mi o mo pe nnkan min in tun si n bo. Lojo Satide ni mo lo siluu Yola, ojo Sande ni mo too pada de. Laaro ojo Monde ni mo ri atejise ipade pajawiri to fe e waye niluu Abuja, mi o le lo nitori pe o re mi, sugbon nigba to maa ya lojo Monde naa, mo gbo ninu iroyin gege bi eyin naa se gbo o. titi di bi mo se n soro yi ni won ko tii so o kan mi leti, tabi pe ki won fun mi niwe (officially) pe looto ni. Mo si mo daju pe a ti ni iwe ofin tuntun ninu egbe ti Alaga wa, Uche Secondus bu owo lu losu kejila odun 2017. Eda e wa lowo mi bayii, maa si ka a fun yin, oju iwe kokandinlogorun, abala kewaa, eyo kefa (Page 99, Chapter 10, Section 6). O so pe “Ipinu ti won ba seleyin omo egbe lai je pe won pe e si akiyesi, tabi pe won fesun kan an lai ranse pe e lati fun un ni anfaani lati le je ko wa a so tenu e, ko nii fese mule.”

Ofin yii gan an lo je pe Uche Secondus lo bu owo luu funra e losu kejila odun to koja leyin ti won yan an, mo wa bere sii woye pe, to ba je pe bi nnkan se ma maa lo re e, mo ni lati loo koju awon igbimo to n fiya je omo egbe (disciplinary committee) to ba je pe mo se, ti mo si mo daju pe mi o se ese kankan. Ko da a, akowe wa to jokoo legbe mi yii naa ko se ese kankan, sugbon won so pe won ti le wa danu ninu egbe. Nigba tawon egbe oselu min in n gbiyanju lati ni awon omo egbe repete, se ni Uche Secondus n le awon eeyan ti won le fowosowopo lati mu ilosiwaju ba egbe, ki idibo odun 2019 le je eyi ta a se nirowo-irose.

Mo fe e so pe Uche Secondus ti wa ninu egbe yi, o ti pe, o ti di opolopo aaye (position) mu, o si mo gbogbo nkan to n lo patapata ninu egbe yi nipinle Ogun. Sugbon sa, eleyi kii se akoko won ti won yo maa ba liana egbe oselu yi je. Nigba ti Ogbeni Olusegun Mimiko de ni nnkan bi odun meloo kan seyin, o wa sipinle Ondo, won ni alaga to niwa tutu nigba naa, iyen Ogbeni Ebenezer Alabi, won so fawon igbimo egbe l’Ondo pe a fi ki won tu igbimo naa ka, ki alaga ati gbogbo won si kowe fipo sile, ibi ti ipile wahala to n sele l’Ondo ti bere ni yii, to je pe PDP ko lese nile mo.

Bakan naa lo tun ri nipinle Edo, leyin e lo tun de ipinle Ekiti. Nigba ti Ayodele Fayose n se awon asise to po, to n hu iwa talo fe e mu mi, gbogbo bi Fayose se n se ni gbogbo won n ri, ti won ko si pe e sakiyesi, ti won ko kilo fun un. Ni bayii ti esi idibo to koja ko koju rere si wa, won wa n gbiyanju lati wa ewure ti won fe e fiya je.

Gege bi emi se mo pelu awon eri aridaju, emi si ni ojulowo alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun. Oro laarin ilana ofin (rule of law) ati aib’ofin mu (illegality). Uche Secondus n sagbateru iwa ti ko b’ofin mu ninu egbe oselu PDP, maa tun je ko ye e yin pe ko si nnkan ti owo ko le se. Ladi Adebutu nigba to darapo mo egbe wa ni nnkan bi odun merin seyin, emi gan an ni mo so pe ki won gboju fo awon nnkankan da fun un (waiver), to le je ko gbapoti, eemeji ni mo lo siluu Abuja lati gba waiver fun won. Nnkan to si lo lati fi de ipo to wa lonii niyen, mi o si lero pe oun gan an lo tun ye ko maa da wa laamu ninu egbe oselu PDP lonii. Mo ti wa ninu egbe oselu PDP lati ogun odun seyin, mi o tii figba kan kuro ninu egbe naa, mo le so fun yin pe bo se wa bayii, Uche Secondus da awon omo egbe to po ju mo (highest bidder), eni to ba ni owo to po ju lo maa wa ninu ilana yii, mo mo, mo si le so fun un yin pe Ladi Adebutu ti gbiyanju gbogbo agbara e lati pew a s’odo ara e pelu omo to le ni bilionu naira, sugbon pelu ojo ori mi yii, mi o le se nnkan to maa pa eri okan mi lara, eri okan lo se koko ti mo si maa tele. Wi pe mo tele eri okan lo mu wa de ipo ta a wa loni yii.

Ladi Adebutu lo n sise lodi si wa, a si ti lo sile ejo, idajo wa lowo wa, ma a fun yin ni eda e. Igba to ya, won tun pada lo sile ejo kotemilorun, to si tun je pe se ni ile ejo kotemilorun da ejo naa nu lodun 2017, won tun gbe ejo naa dide, sugbon ti won tun pada da a nu ni nnkan bi ojo mewaa seyin. Iwe idajo yen ni mo mu lo siluu Abuja lose to koja, nitori pe igbeyin ejo naa niyen, ayafi ti won ba fe e lo sile ejo agba (Supreme court). O ya mi lenu pe Uche Secondu de ipo agbara nipa ona to b’ofin mu yi, nitori pe nigba ti Makarfi bori ejo yi nigba naa, igba yen gan an lo le seto ipade gbogboogbo, eyi to gbe Uche Secondus wole gege bi alaga. Uche Secondus n gbiyanju lati to ilana ti bofin mu niluu Abuja, sugbon bo ya o fe, tabi o ko, emi ni alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, to ba fe e se nnkan min in to yato eyi, ile ejo lo maa lo lati loo lodi si idajo to gbe mi wole gege bi alaga leyin ipade gbogboogbo naa. Ko si oro pupo lati so, maa so fun yin pe ilana ofin orileede yi duro digbi, mo si gbagbo ninu e gidigidi.

Bi won ba le mi danu kuro ninu egbe, ti won tun  le akowe egbe naa danu, igbakeji mi wa nibi, oun naa a soro, boya to bat un ya, bi ko ba te won lorun, boy a won tun le gbe elomin in dide lati ropo wa. Iyen gan an ko ni oro to wa nile bayii, nitori pe emi gan an ni ojulowo alaga egbe oselu yi nipinle Ogun, sugbon to ba di ola, ti idajo min in lati ile ejo to kun oju osuwon ba so pe emi ko, ko si nnkan to tun n di mi lowo lati ko gbogbo eru mi kuro ninu ofiisi yi, ki n si gba ile mi lo.

Looto ni mo n palemo fun asiko ifeyinti mi, sugbon mi o ni fi aga yi sile titi di osu kerin odun 2020, nitori pe ipade gbogboogbo to gbe mi depo yi waye lona to bofin mu, a si ti lo sile ejo, ile ejo naa tun fese e mule pe emi gan an ni eni to to lati wa nipo naa, bee ni won tun so pe gbogbo nkan to to la ti se.

Mo wa n fi asiko yi so fun gbogbo awon omo egbe lati lo maa sise won, ki won si jara mo gbogbo nnkan ti won ba n se, ki won si je ka fowosowopo sise papo, mimi kan ko le mi wa labe bo ti le wu ko ri, egbe akata mi si ni akoso egbe oselu PDP ipinle Ogun wa.

AWIKONKO: Se nnkan ti e so ni pe Ladi Adebutu lo n da egbe yi ru nipinle Ogun?
BAYO DAYO: Mi o so be e o, e ma si mi gbo rara, mi o so pe ladi Adebutu lo n da egbe ru nipinle Ogun, nnkan ti mo so ni pe oun ati baba e lo n na owo inakuna, to n gbe owo kaakiri, to si je ko maa fa gbogbo rogbodiyan to n sele ninu egbe. Kii se pe o n da egbe ru, nitori pe oun naa n wa nnkan to maa je kaakiri ni. O loun fe e se gomina ni tipa-tipa.

AWIKONKO: Bawo ni ti Seneto Buruji Kasamu?
BAYO DAYO: Bi kii ba a se ti Seneto Buruji Kasamu ni, egbe oselu PDP ko ba ti ku tipetipe nitori pe oun nikan lo n na owo ta a fi n gbe egbe yi duro lati bii odun marun un seyin. Nigba te e debi, e ri awon eso alaabo, e si rii pe gbogbo ayika ileese wa lo mo toni-toni, e si rii pe gbogbo nnkan lo wa gege bo se ye ki won wa, tawon osise naa si wa. Buruji Kasamu nikan ni apo owo egbe yi, to ti n na owo lori egbe yi. Isinyi ta a wa ni adari wa, Otunba Gbenga Daniel lo je pe a ma loo ba oun naa, bo tile je pe o le se, o si le ma se. OGD naa tun je eni kan pataki to le na owo lori egbe oselu yi, mo si nigbagbo pe oun naa ti setan lati fowosowopo pelu wa ka si le sise papo gbe egbe yi soke.

AWIKONKO: E ti so pee yin ni ojulowo alaga egbe yi, sugbon ki lo de ti e ko maa soro jade ni gbogbo igba bi awon to ku se n se?
BAYO DAYO: Se e ri, agba ti ko ni omi ninu lo n pariwo. Ti e ba n sise, e o le ri wa nita, e lo o wo awon egbe oselu APC, e ko le rii pe ki won pejo lati jokoo iru ijokoo ta a jokoo yi ninu ofiisi wa, kii se pe won ku, won ni ipinu ti won, mo fe e ki e mo pe kii se pe a o sise, sugbon mo fe e fid a yin loju pee nu yoo ya yin to ba di asiko idibo, ti e ba ri wa nita, nnkan ta a si n se niyen. O seni laanu fun w ape agbenuso wa ta a ni nigba yen, eni to n soro jade sita fi wa sile lo sinu egbe oselu ADC, won tan an je lati pe e lo sinu egbe naa. Baba Obasanjo ti so fun gbogbo awon to ba fe e gboro pe ADC, maa ni gomina lodun 2019, ti mi o si nigbagbo si eyi. Agbenuso wa ta a ni lasiko yi, omo kekere ni, to si je ki won tan an je, e je ka duro de osu keji odun 2019 lati mo nnkan to n loo. Nnkan to sele ti mo fe e je ki e mo ni pe, a ti ni agbenuso egbe tuntun, ti ise e ko si ni pe e bere, igba naa le sese ma maa gbo awon oro olopolo to ma maa jade bayii.

AWIKONKO: Iroyin tuntun ta a tun gbo ni pe Seneto Lanre Tejuoso ti darapo mo egbe yin, se looto ni, ati pe se aaye si sile fun un?
BAYO DAYO: Beeni, emi naa gbo nipa e, sugbon mi o tii le fidi e mule. Aaye repete lo sile fun un, ta a sit un maa gba towo-tese. Idagbasoke ta a tewo gba ni pe Lanre Tejuoso dara po mo wa, inu mi dun si, mo si nigbagbo pe to ba pada de lati ilu Abuja, ma ape lori aago, maa si pe sipade pe ko je ka jo so asoyepo, lati le mu ilosiwaju ba egbe yi.

BAYO DAYO: Ki le wa  a fe kawon omo ipinle Ogun nipa egbe oselu PDP?
AWIKONKO: Mo fe ki won mo pe egbe oselu PDP kan soso lo wa nipinle Ogun, emi si ni alaga gbogbo won, gbogbo awon to n so isokuso kaakiri naa n wa nnkan ti won maa je ni. Bee ri eeyan to n fo l’oke, nnkan to maa je lo n wa, eni to n lo lori omi ati nisale ile, nnkan ti won maa je naa ni won n wa. Gbogbo awon ti won n so pea won je bakan ninu egbe yi ni ofin ijoba ko da mo, idajo wa lowo wa nibi to so pe Adebayo Dayo ni alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, eni to ba si fe e yi pada, dandan ni ko lo sile ejo, bo tile je pe opo igba ni won ti lo sile ejo to je pe ete ni won ba bo nibe, idi ni yii ti won fi gbe owo lo fun Secondus pe ko ba won se e, nitori pe agbara won ko ka. Nnkan to n sele gan an ni mo ti salaye fun un yin yi, ko si nkan to ju be e lo.

PÍN-IN KÁÀKIRI