WAHALA L'EKITI: WON LAWON APC FE E PA GOMINA FAYOSE MO ILE IJOBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 11, 2018

WAHALA L'EKITI: WON LAWON APC FE E PA GOMINA FAYOSE MO ILE IJOBA


Iroyin to n ko kaakiri orileede Naijiria lasiko yi paapaa nipinle Ekiti latari ti idibo gomina to n bo lojo Satide opin ose yi ko dun mo eeyan ninu rara, lori bi won se so pe awon olopaa ati eso ologun loo fi afefe taju-taju, iyen teargas sinu ile ijoba ti Gomina Kayode Fayose wa.
Bo tile je pe AWIKONKO ko tii le fidi iroyin naa mule, sugbon ohun ta a gbo ni pe awon egbe oselu alatako nipinle Ekiti, iyen APC ni won ran awon olopaa ati eso ologun pe ki won loo se Gomina Fayose lese nibikibi ti won ba ti rii.
A gbo pe ni nnkan bi aago mewaa aabo aaro onii Wesde lawon eso ologun atawon olopaa ologun kowo rin lo si ayika ati agbegbe ile ijoba ti Gomina Fayose n gbe, ti won si bere sii yinbon kaakiri agbegbe naa, ti won tun so afefe taju-taju (teargas) naa sinu ile naa, to si je pe nigba to maa bale, oju Gomina Fayose lo wo lo.
Lesekese la gbo pe Fayose subu lule, to si daku. Awon eso e atawon ti won wa pelu la gbo pe won sare bere sii da omi lee lori, ti won si n toju e.
Titi di asiko ta a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe Gomina Fayose ko tii riran daadaa, to si wa nibi to ti n gba itoju lowo. Bee la tun gbo pe awon eeyan to wa ninu ile ijoba naa ko tii le jade sita, tabi pe kawon to n bo lati ita wole nitori bi won se so pe gbogbo ayika naa lawon olopaa ologun ti won lawon egbe oselu APC lo ran won yi ka.
Bakan naa, lesekese tisele naa n lo lowo ni won ti lo ero ayelujara ti Gomina Fayose, iyen Twitter lati fi gbe iroyin naa jade sita, kawon eeyan le mo bo se n lo.
Lara awon aworan to te AWIKONKO lowo niwoyii.
PÍN-IN KÁÀKIRI