NITORI IKU OBA AGURA TILUU GBAGURA, OMODO AGBA BANUJE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 13, 2018

NITORI IKU OBA AGURA TILUU GBAGURA, OMODO AGBA BANUJE

Beeyan ba ri okan lara awon agba gbajumo sorosoro ori redio nni, Alaaji Moruph Adegboyega tawon eeyan mo si Omodo Agba nibi to ti n sunkun nirole ojo Tosde to koja yii, yoo ro pe okunrin naa fe e gba nnkan to se pataki lowo Oba Halidu Olaloko to je Agura tiluu Gbagura to waja ni.


Gege bi awon to firoyin naa to AWIKONKO leti se so, ko si nnkan ti won lo n pa ilu mon n ka sorosoro naa, to maa n se eto iriri aye to pe ni Awodi Oke nileese redio Family to wa niluu Abeokuta bi ko se ti iroyin iku Oba Halidu Olaloko to ba a lojiji.

Ohun ta a gbo ni pe bo tile je pe Omodo Agba ko koko gbagbo pe otito niroyin iku Kabiyesi naa nigba to gbo, sugbon nigba tawon to sunmo on aafin Gbagura fidi e mule fun un, se lo bu sekun bi omo ikoko ti ko ri oyan mama e mu fojo meta.


Won niyalenu lo je fawon to wa lodo Omodo Agba lasiko naa nigba ti won ri to bu sekun nitori pe awada ni won koko pe e, sugbon nigba ti won ri bi omije se n bo loju e boroboro ni won ba sare gba a mu, ti won si bere sii ro o.

A gbo pe okan lara awon Oba ilu Egba to sun mon on Omodo Agba ni Oba Agura je, to si je pe Kabiyesi naa pelu awon ti okunrin naa ma lo n gba amonran ati iwadii lodo e ko too dagbere faye.


Odun metadinlogbon ati osu mesan an la gbo pe Oba Halidu Olaloko fi je gege bi Kabiyesi, ojo kejidinlogun osu kewaa ni yoo pe odun mejidinlogbon ti Kabiyesi fi je ko too dagbere faye leni odun mejidinlogorin.

AWIKONKO gbo pe, aago merin irole onii Fraide ni won yoo sinku Kabiyesi si ile e to wa ni Obasanjo Hill Top, Abeokuta ni ilana Musulumi.

PÍN-IN KÁÀKIRI