AMBODE SORO NIPA TINUBU, NI WAHALA BA BE SILE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 18, 2018

AMBODE SORO NIPA TINUBU, NI WAHALA BA BE SILE

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Pelu bi nnkan se n lo yii, o jo pe, lojoojumo loro ibo gomina ipinle Eko n le si i, ti gomina ipinle naa, Akinwunmi Ambode ko ti i rojutuu si bi yoo se ri saa e lo leekan si i.

Nibi inawo kan ni won tun ti pade, Gomina Akinwunmi Ambode ati Bola Tinubu pelu awon eeyan jankan-jankan mi-in ni won wa nibe lojo naa. Oga agba ileeefwopamo Zenith, Jim Ovia lo se ifiliole iwe kan, bi Bola Tinubu ti soro tan, ti won ni ki Ambode naa o wa soro, ni iyen ba fi towo-towo ati awada so wi pe, niwon igba ti Asiwaju oun ti soro, iyen Bola Tinubu, ki loun tun fe wi mo.

Oro to so ree, nibe gan-an lawon eeyan ti bere si gbe e kiri wi pe, o jo pe Gomina naa ti tete n gba f’Olorun nipa bi awon omoleyin Tinubu atawon eeyan kan se gbogun ti i wi pe ko tun ni i se ijoba Eko leekan si i.


Lojo Aje Monde, ana ni iroyin ohun gba igboro kan, o fe ma si iwe iroyin ti ko gbe e, ohun ti kaluku won si fi se akole ni pe, Akinwunmi Ambode, gomina Eko ti so pe, oun ko gbodo soro kan bayii, niwon igba ti Asiwaju Bola Tinubu ba ti soro. Bo se ti so o lawon eeyan ti n lo oro ohun mo wahala to wa nile, nipa bi awon kan se so pe Asiwaju Bola Tinubu ko setan lati ti i leyin mo, ati pe niwon igba ti ko ti fun oun laaye, o je pe gomina naa ti setan lati maa palemo eru e mo. 
https://mpulse.mtnonline.com/#utm_source=awikonko&utm_medium=banner&utm_campaign=mpulse

Itumo tawon eeyan kan ninu oselu n fun akole to gbode kan ohun niyen, se ohun ti Gomina si gba lero ni pe, erin ko gbodo fon ki omo e naa tun fon, sugbon bi oro ohun ti jade lenu e lawon eeyan ti sare lo o mo ohun to n sele lowo niluu Eko, ti won si n gbe e kiri pe, o dabii eni pe Ambode ti fe maa gba f’Olorun.

Te o ba gbagbe, bi okunrin oloselu omo Epe yii se fi ipinnu e han lati dije loruko egbe oselu APC leekan si i lokunrin onimo nla kan, Babajide Sanwoolu, eni to ti sise kaakiri ileefowopamo, to tun ti ba Femi Pedro ati Bola Tinubu sise papo lasiko ti won sejoba Eko naa so pe; ipo Ambode gan an lo wu oun julo ninu ibo odun 2019.


Bi wahala se bere ree, paapaa bi awon kan ti won je alatileyin Bola Tinubu se duro gbon-in ti Babajide Sanwo-Olu leyin, ti gbogbo alaga ijoba ibile idagbasoke metadinlogota to wa l’Ekoo si so pe okunrin naa lawon n ba a lo. Pelu gbogbo aduroti ti won n fun yii, ohun kan ti Asiwaju Bola Tinubu si tenumo ni pe, ibi ti awon agbaagba egbe ba ti lo loun n lo, nitori awon gan-an lopo egbe, ati pe ola tiwon gan-an loun naa fi n mi.

Nibi ti oro wa niyen, nigba ti won si jo pade nibi apeje, ti Gomina Ambode fi oro dapara wi pe niwon igba ti Asiwaju ti soro, ki loun tun fe so mo, nibe yen gan-an lawon eeyan ti so pe o dabii eni pe okunrin naa ti fe gba f’Olorun oba!

Lara awon eeyan pataki to wa nibi ifilole iwe ohun ni igbakeji aare orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo, Akintola Willams; oga agba ileese Channels Television, John Momoh; Tony Elumelu, Folorunsho Alakija; Alagba Christopher Kolade; Pat Utomi ati bee bee lo.

PÍN-IN KÁÀKIRI