Amosun fẹẹ mori ọmọ Ọṣọba mabẹ, Niyẹn ba sọ pe ere ọmọde lasan ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 12, 2018

Amosun fẹẹ mori ọmọ Ọṣọba mabẹ, Niyẹn ba sọ pe ere ọmọde lasan ni

Ọnarebu Olumide Ọṣọba, to jẹ ọmọ Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, ti pariwo sita pe gbogbo ọgbọn ti Gomina Ibikunle Amosun fẹẹ fi mu ori oun mọ abẹ loun mọ, ṣugbọn oun gbọn ọn ju u lọ, nitori ipo to foun ninu ipinsipo lati ṣoju Abẹokuta South nile igbimo aṣoju-ṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, oun ko fẹẹ nitori ko tọ ọ lọna to yẹ.


Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo ti sọ pe, lakọọkọ, ẹkun Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode atiỌdẹda loun ti jade lọdun 2011 si 2015 nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, ki lo wa de ti Amosun fi kọ orukọ oun sabẹ Abẹokuta South, o ni ere ọmọde loun kaa si.

Nitori ko sigba kankan toun ni lọkan lati fawọn eeyan oun silẹ bẹẹ loun si wa pẹlu wọn ni gbogbo igba.

O ni bawo lawọn ti wọn ko to irinwo yoo ṣe wa joko sibi kan lori awọn ọgọfa miliọnu awọn eeyan.

Olumide tun sọ pe nigba toun fẹẹ forukọ silẹ fun idibo, wọọdu kẹta ni Owode labẹ ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode loun ti forukọ silẹ, oun ko si figba kankan bawọn ṣe oṣelu ri ni Abẹokuta South ti Gomina ni koun ti jade.

O ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun ri orukọ oun nibi toun ko ti bawọn ṣe oṣelu ri ati pe ko sigba kankan toun bawọn jokoo papọ pin ipo, bẹẹ ni ko sẹni to jẹ koun gbọ.

O wa yara ẹ sọtọ gedegbe lori orukọ ti wọn gbe jade naa.

Lori idije pamari eyi ti ẹgbẹ lapapọ fọwọ si fun ti ibo 2019, O ni oun ṣetan lati dije nilana ti wọn gbe kalẹ fun ẹkun Owode, Abẹokuta North Ọdẹda toun ti wa, oun ko bawọn si ninu ibo ọtẹ tawọn kan gbe kalẹ.

Gbogbo awọn to ri orukọ ti wọn ni Amosun gbe sita naa ni wọn gba pe Gomina naa fẹẹ fi da wahala silẹ laarin awọn ẹyin Oloye Oluṣẹgun Ọsọba laimọ pe awọn yẹn naa gbọn ọgbọn oṣelu juu lọ.

Ni bayii, a gbọ pe iran lawọn eeyan naa n wo gomina ti wọn si n reti ibi ti wọn yoo gba mu, ti ẹru yoo ti ba a.

Bee ni Olumide Osoba tun so pe awon kan ti n dunkoko lati pa oun danu nitori toun gba ipinisipo ti Gomina Amosun. O so pe latigba toun ti fi ehunu han ni won ti n dunkoko mo eni oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI