Awon olopaa yinbon pa adigunjale kan ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 1, 2018

Awon olopaa yinbon pa adigunjale kan ni Sagamu

Opo awon ri won wa ninu moto akero ti Young Shall Grow tawon adigunjale da duro lojo Wesde ose to koja yi ni won ko le tete gbagbe ojo naa, paapaa bi ori tun se ko won yo lojo naa.

Oku odaran naa
Ipinle Eko la gbo pe moto naa ti n ko awon eeyan lo rin irinajo lo sile Yibo, ki won lawon adigunjale to da won duro lagbegbe Ogbere lopopona Sagamu si Benin.

AWIKONKO gbo pe nibi ti won ti le gbogbo won bo sile lati maa a fibon ba eru won lawon kan to n koja lo ti tawon olopaa lolobo, tawon yen anaa si teko leti de be.

Won ni bi won se foju kan moto awon olopaa ni won koju ibon si won, ti won si bere sii yinbon funra won, nibe la gbo pe ibon ti ba eni kan ninu won, to je pe esekese lo ku.

Bi won se lawon to se rii pe ibon ti ba okan lara won to da bii pe oun lo lewaju won loo jale naa, lo mu kawon to ku ba ese won soro, ti won na papa bora.

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu to fidi isele naa mule fi idunnu e han lori bi won se pa okan lara won, to loun ti pase pe ki won tete wa awon odaran to ku ri nitori pe ara oun ko le gba a lati maa ba odaran gbe inu ilu kan naa.

Awon ohun ija oloro bii ibon, ayderu ibon kekere ati oogun abenugongo la gbo pe ri gba lara odaran ti won pa danu naa.

PÍN-IN KÁÀKIRI