Eni To Ba Setan Lati Le Buhari Danu Ni Mo Fee Tele - Adebanjo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 2, 2018

Eni To Ba Setan Lati Le Buhari Danu Ni Mo Fee Tele - Adebanjo

...Mi o le ba eni to ba fee ki Buhari pada leekeji se papo 

Agba Afenifere nni Oloye Ayo Adebanjo ti so lojo Aiku Sannde pe oludije sipo Aare to ba setan lati le Aare Mohammadu Buhari kuro lori ipo ninu ibo Aare loun yoo sise pelu e.


O soro yii lakooko ti igbakeji Aare tele lorileede yii, to tun fee dije fun ipo Aare lodun to n bo labe egbe oselu PDP, Alaaji Atiku Abubakar atawon eeyan e loo sabewo sodo e niluu Eko.

O so siwaju pe oun ko le ba enikeni to ba fee ki Buhari pada sejoba leekeji se papo. O ni bi a ba ni ka so t'ododo Ijoba to wa l'ode yii ti mu ijakule ba awon araalu. Gbogbo Oba ni won si n gba lati ma se je ko pada wa mo leekeji.


Bakan naa lo so pe ninu gbogbo awon oludije to ti n jade fun ipo aare naa Atiku nikan lo le s'atunto tawon araalu n so.

O wa n'ipo ti oro aje wa ni Naijiria ko bojumu to. Bee lo wa ro oludije naa lati sa agbara e to ba dori ipo naa.


Ayo Adebanjo tun so pe egbe Afenifere ti satileyin fun Buhari ri, iyen nigba to fi jade labe egbe oselu ANPP, sugbon ni bayii ko si nnkan to jo o.

Ninu oro Atiku Abubakar, o dupe lowo Oloye Ayo Adebanjo fun bo se gbawon lalejo, o so pe gbogbo agbara loun yoo sa lati rii pe ayipada de ba orileede yii bi won ba foun laaye lati di Aare orileede yii.

Bee loun naa so pe eto atunto tawon eeyan pariwo d'ohun amulo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI