...Mi o tete mo pe ayederu iwe-eri ni won gbe le mi lowo
Lati fopin si idaamu ti Minisita fun eto isuna
owo, Arabinrin Kemi Adeosun n koju latari ayederu iwe eri isinjoba ti won so pe
obinrin naa n lo, ni bayii o ti salaye lekunrere bo se ko sowo awon onijibiti
ti won ko o sinu wahala ohun.
Adeosun |
Ninu leta ikowe-fise-sile to fi sowo si Aare
Muhammed Buhari lo ti salaye lekunrere bi oro ohun se ba oun lokan je gidigidi.
Ninu leta ohun lo ti salaye pe ilu London ni won
bi oun si, ti oun si ka gbogbo iwe oun nibe ki oun too wa si Nigeria lasiko ti
oun pe eni odun merinlelogbon.
Kemi Adeosun fi kun oro e pe, “Saaju ki n too wa
si Nigeria, eekookan ti mo maa n wale, a maa n wa se olide ni, gbogbo igba ewe
mi pata, ilu oyinbo ni mo ti lo o. Nigba ti mo si pada si orile-ede yii, mo ti
wa leni odun merinlelogbon. Asiko yen gan an ni oro isinjoba waye. Lojuese naa
lawon eeyan ti so pe, mo ti koja eni ogbon odun, fun idi eyi, mi o letoo lati
sinjoba mo, sugbon anfaani wa fun mi lati gba iwe eri, eyi ti yoo safihan wi
pe, mo ti koja ojo ori to ye ko se e ni mi o se ba won kopa.”
Obinrin to ti lo odun meta o le ninu ijoba
Muhammed Buhari yii fi kun un pe, oun ko mo pe awon eeyan ti oun gbe ise naa
fun lati ba oun gba iwe eri, ayederu ni won se fun oun. O ni, “Mi o de inu ogba
NYSC ri, bee ni mi o mo bi won se n se nibe. Awon eeyan ti mo fokan tan ni won
gbe ayederu le mi lowo.
“Mi o sese maa lo iwe eri ohun nipinle Ogun, ti
ko si si wahala kankan ki awuyewuye yii too bere. Gege bi enikan to korira iwa
ibaje, eyi gan-an lo mu mi kowe fipo mi sile lojo Eti, Fraide, ojo kerinla osu
kesan-an kuro ninu ijoba Muhammed Buhari. Mo dupe lowo Aare fun anfaani nla ti
won fun mi, bee ni mo dupe lowo gbogbo awon ta a jijo sise pelu, mo nigbagbo wi
pe, ojo ola orile-ede yii yoo dara, nitori ise takuntakun ni Aare Muhammed
Buhari n se.”