NNKAN TO N BA MI NINU JE JU - ALAKE TILE EGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 11, 2018

NNKAN TO N BA MI NINU JE JU - ALAKE TILE EGBA

Beeyan ba wa ni Aafin Alake tile Egba lojo Monde to koja yii, to gbo bi Alake tile Egba, Oba Michael Adedotun Aremu Gbadebo, Okukenu kerin (IV) se n soro, yoo mo pe inu Kabiyesi naa ko dun rara pelu awon oro to n so.


Nibi ipade ti Oba Gbadebo se pelu awon oniroyin lati fi saami ayeye ojo ibi odun marundinlogorin (75) to pe ni Kabiyesi ti soro nipa nnkan to n ba a ninu je ju, to si n rawo ebe pe ki atunse tete wa lori e.

Ko si nnkan meji ti Kabiyesi naa so pe o n je edun okan foun bi ko se owo tawon omo Yoruba fi mu awon aso ibile, paapaa owo tawon Egba fi mu aso ibile won, iyen aso Adire ti won tun n pe ni Kampala.

Oba Gbadebo ni gbogbo igbiyanju oun lati rii pe awon omo Egba tewo gba aso Adire, toun si n polongo e loore-koore, pabo lo si n ja si.

Kabiyesi naa so pe ko si aso to buyi lara ninu gbogbo aso to wa lagbaye to Aso Adire, idi ni yii tawon Egba fi gbodo pada lati lo maa wo aso naa, lati gbe asa ati ise won laruge.


O ni lati odun ketala toun ti wa lori oye gege Oba Alake, loun ti n polongo pe kawon omo Egba maa wo aso Adire, sugbon to je pe won ko mu lokunkundun bi awon aso oke okun.

Bakan naa ni Alake tile Egba tun so pe ko si ounje to dun to Iresi Ofada to je tibile wa, sugbon sibe, ko seni to n je e to awon Iresi oke okun.

O wa rawo ebe pe kawon Egba paapaa awon Yoruba tewo gba aso ibile, iyen Adire, ki won si tun maa je Iresi Ofada lati le fi gbe asa ati ise Yoruba laruge.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI