BAWO LO SE N LO FOONU ALAGBEKA IGBALODE? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 20, 2018

BAWO LO SE N LO FOONU ALAGBEKA IGBALODE?


Mo ki gbogbo eyin ololufe iroyin AWIKONKO pe e ku opin ose yi, e ko nii pare mo aye lara pelu bi e se n tele wa ni gbogbo igba. A tun ti de ni opin ose yi gege ba a se maa n mu abala Ajoro wa fun un yin. Opo eyin ololufe e wa naa la n ri atejise yin ni gbogbo igba, paapaa bi e se n kan saara si wa. Olorun a maa nife eyin naa bi e se n nife wa.

Ohun ta a tun mu wa lose yi pe ka jo gbe yewo ni ti foonu alagbeka igbalode, ipa to n ko ati awon akoba to n se, iyen lori bi a se n lo o latigba to ti de.
Bi ko ba si ti aaro, gbundunku ni awon Agbe ko ba wa; bi ko ba si ti osun, rako-rako ni Aluko ko ba maa wo. Bi ko si ti sese-efun ni, Lekeleke ki ba ma ti l'ewa kankan. Bi ko ba si ti Eledumare to da laakaye mo omo eda Adamo, n se lomo eda ki ba ma ti yato si sigidi lasan-lasan. Amo tori pe Eledumare ti jogun opolo fun wa, eyi mu k'omo eeyan ni ero arojinle lati sawari ona igbayegbadun otun.
Ojojumo ni imo eda tubo  n jinle si ninu imo ero. Okan pataki ni ero foonu alagbeka je ninu awon ero igbalode ti ko se e fowo ro ti seyin lawujo. O fere e je pe gbogbo eda eeyan abemi to n gbe loke eepe lo ni ero yii lowo. 
Oore ti ipe-e-n-peju n se eyinju o kere. Ise kekere ko ni ero foonu alagbeka naa n se fomo eeyan. Ero yii ti mu ki ona igba ikan-sira-eni tubo rorun debi pe bi eeyan n be ni koro iyara re, o le maa kan si eni ti n be loke-okun ti yoo si maa gbohun re ketekete.
Eeyan le gbe ehinkule mo iye obi to yan niwaju ita elomiiran. Eni ti n be l'oko le mo ohun ti n sele nile, bo ba ti ni ero foonu alagbeka igbalode.
Bi imo ijinle eda se n po si naa ni atunse  n de ba ero igbalode yii. Ni bayii ero naa ti laragbara debi pe a le lo o lati sise ero komputa, ero ayaworan (kamera) atawon ero miiran. A le fi ero foonu alagbeka pe eeyan to jinna si wa, a le fi te ateranse, a tun le fi wo intaneeti.
Anfaani ati iwulo eda lawon nkan yii wa fun, won si tun ti mu ki igbesi aye rorun. Amo ero foonu alagbeka igbalode yii ti so opo eda di alainifeni adanida mo. Bee lawon kan ti di oku onroro. 
Nigba kan ri, bi ijamba oko ba waye tabi ijamba miiran sele tawon eeyan si fara kaasa ninu awon isele naa. Ere bi awon to ba wa nibe yoo se se iranlowo fun won tiwon yoo si doola emi awon eeyan ni awon to ba wa nibe yoo maa sa. Amosa a, oro naa ti yida bayii.
Aye ti sojude! Ero alagbeka igbalode ti so awon eeyan di alainife ara won debii pe bi iru ijamba ta n so yii ba waye, kaka ki won wa bi won yoo ti doola emi awon eeyan, kaluku won yoo yo foonu re jade ti yoo si maa ya aworan lati fi ranse sori ero ayelujara titi opo awon ti ijamba sele si naa yoo fi gbemi min in.
Ko si oore ti ipa n se epon. Yiya aworan ijamba lati fi ranse sori ikanni ajolo lori ero ayelujara ko sanfaani kankan feni ti ijamba se si, bi ko se pe ka se iranlowo fun onitohun lati doola emi re. Iru oore bayii kii gbe. Koda bi eeyan ko san wa lesan re, Eledumare yoo san esan oore fun wa. Sugbon to ba je pe aibikita wa nipa yiya aworan dipo sise iranwo lo mu ki emi enikan bo sinu irora. Eledumare yoo beere eje re lowo onikaluku.
Bi eeyan ba fi laakaye se ohunkohun fun igbayegbadun eda. Laakaye naa lo ye ka maa fi se amulo re.
Lati owo: Aremo Jah
(+234)-817 098 1831

PÍN-IN KÁÀKIRI