EFCC MO DE O - FAYOSE SORO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 17, 2018

EFCC MO DE O - FAYOSE SORO

Bo ti ku iseju kan ki aago kan osan lu lojo Tusde to koja yi, ni gomina ipinle Ekiti tele, Ogbeni Peter Ayodele Fayose yo si ofiisi ajo EFCC toun ti baagi kan lowo, funra e gan-an lo wa fara e kale fun ajo ohun.

Saaji asiko yii gan-an ni gomina ipinle Ekiti tele yii, eni to sese pari saa e lana-an Monde kowe si ajo naa, ohun to si so ni pe, gbogbo ibeere ti won ba ni pata loun setan lati wa da won lohun e, ni kete ti oun ba ti pari isakoso oun lojo keedogun osu yii.

Ninu leta ohun lo ti so pe ki ajo EFCC maa reti oun laago kan osan ana; ti i se ojo Isegun ojo kerindinlogun, sugbon nigba ti aago kan ku iseju kan pere ni Fayose yo bii ojo si ileese naa pelu aso alawo ewe, pelu akole yii lara aso ohun EFCC mo de o!

Ki i se oun nikan lo wa lojo naa, bo se n bo ni gomina ipinle Rivers, Nyesom Wike ati Femi Fani Kayode, okan lara omo egbe oselu PDP, to tun ti figba kan je minisita ri  lorile-ede yii tele e wa.

Sa o, ko too di pe awon osise ajo ohun mu Fayose wonu ofiisi won lo, gomina ipinle Ekiti tele naa soro, nibe gan-an lo ti bu enu ate lu bi awon eso ileese naa ti se wa laduugbo e lati ana. O ni, nise ni won n dode oun kiri, saaju asiko ti oun so pe oun yoo yoju sileese naa.

O ni, “O je ohun to bani-lokan-je wi pe awa eeyan orile-ede yii ki i gba eeyan gbo, tabi fi suuru kun ohun ti a ba n se. Emi ni mo ko leta si ajo EFCC wi pe maa yoju ni kete ti mo ba ti kuro nipo gomina, koda mo tun ko asiko ti maa de ofiisi won sinu leta mi paapaa ati ojo ti maa wa, eyi ti mo se loni-in. Sugbon o jo mi loju nigba ti mo tun ri awon eso EFCC  ti won n pooyi adugbo mi lati ana. Emi ree o, mo ti de bayii, omoluabi to maa n soro, ti eeyan maa n ba a bee ni mi, gbogbo ohun ti won ba fe bi mi pata ni mo setan lati salaye e gege bo se ye mi si.”

Gomina Nyesom Wike to ba a debe naa soro, ohun to si so ni pe, pelu alaafia ara ni Fayose fi de owo ajo EFCC, bee ohunkohun ko gbodo se e. Femi Fani Kayode naa fi kun un pe, o se pataki ki awon fi atileyin awon han si gomina tele naa, nitori e gan-an lawon se ba a wa sibe lojo naa.

Pelu baagi kekere ti Fayose gbe dani ati aso alawo ewe toun ti akole ara e ni won sin in wo ileese won, nibe yen gan-an lawon Wike ati Fani Kayode atawon mi-in ti won ba a debe ti pada leyin e, ti okunrin naa si wo ogba ajo EFCC lo lati lo maa salaye awon ohun ti won fe bi i.

PÍN-IN KÁÀKIRI