IWA OMOLUABI DA LAWUJO WA? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 27, 2018

IWA OMOLUABI DA LAWUJO WA?

Yoruba bo won ni "Iwa ni ewa omo eeyan, Iwa ni oba awure." Nigba ti gbolohun naa tun nipon si i, awon agba tun fi kun un pe "Eefin n'iwa, ko se e fi pamo s'abe aso."


Gbogbo oriki to wa l'oke ti i se afihan bi iwa ti se pataki to lawujo. Ilekun n'iwa bi ko ba si sinu ile, dandan ni ko si sita gbangba. Bi eeyan ko ba n'iwa rere, yoo n'iwa buburu. Sugbon awon oro yoyruba fi han pe iwa omoluabi lo ye omo rere lawujo. 

Iwa eda ni yoo pinnu iru eni to je, Iwa naa ni yoo si se afihan iru eda bee fun araye. Se Yoruba bo won ni Obinrin so iwa nu, o loun ko lori oko. Oba so iwa nu, o lawon ilu ko feran oun. Iwa omoluabi lo n pinnu iru eni teeyan je lawujo.

Oro awon agba kan lo so pe "Olowo se ohun gbogbo tan", sugbon kii se bi ti iwa, se bibii're ko kuku se e fowo ra. Owo ko se e fi ra iwa omoluabi lawujo, bee leeyan o le fi ipo, agidi tabi eeyan mimo soro lati ni iwa omoluabi, lailai.

Emi irele, iteriba ati ibowofunni se pataki tori oun ni yoo finihan gege bi omoluabi eeyan. Amo sa, o seni laanu pe iwa omoluabi ti n sonu lawujo wa. Awon eeyan ko naani iwa omoluabi mo. Omode ko beru lati kan agba labuku. Aya ko beru lati wo oko re nile gbuurugbu. Awon agba pelu ko beru lati re omode je mo.

Itiju ti wa a d'ohun a n gbe ta, iwa omoluabi ti d'ohun agbeko'gi. Ko wa sohun ti n tinni loju mo.  Awon iwa to je iwa itiju tele ti wa dohun asegbayi lawujo wa. Olomoge le wo sokoto lati ilu eko de sokoto lai ni ohunkohun ti yoo tii loju.

Olomokunrin ko itiju, won n gbe sokoto si bebere idi. Ka lut eti ko, yeri s'eti ti wa dohun iyi fawon okunrin asiko yii. Ka puro ta t'owo omolakeji ti wa d'ise aje fawon eeyan. Gbogbo eyi ko se eyin bi omo asegita wa ko se naani epo igi mo. 

Amo ohun to ye'ni, lo ye'ni, okun orun ko ye adie. Bo ti e tun ye adie, sugbon ko ye eni to mu un lowo. Bo si tun ye eni to mu un lowo. Ko bu iyi kun ita baba eni ta maa so o mo.

Iwa omoluabi se pataki lawujo. Iwa rere leso eniyan. Iwa la fi n pinnu aya rere loode oko, iwa naa la fi n pinnu eeyan rere lawujo.

Lati owo: Aremo Jah

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI