AKOROYIN REDIO NAIJIRIA BE SINU ODO L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 2, 2018

AKOROYIN REDIO NAIJIRIA BE SINU ODO L'EKO

Kani kii se pe awon osise ori omi ti afara kẹta (Third Mainland) to wa niluu Eko ko sun asunpara ni, ati pe t'ọsan t'oru ni won fi n sise won, o ṣee ṣe kí wọn má mo pe eeyan bẹ sodo.


Lesekese lọkunrin naa ti sọdá sorun alakeji, ti iroyin to te wa lowo tun je kó yé wa pé akoroyin ileese redio Naijiria ni, ati pe aaro onii, ni nkan bi aago mewaa aabo l'ọkunrin naa binu bẹ sodo lati gbemi ara é.


Bẹ ọ ba gbagbe, losu to koja yi leni kan bẹ sinu agbalugbu omi yi, ti won tete du emi e, sugbon to pada ku sí osibitu.


Àjọ ileese eleto aabo tipinle Eko, Lagos State Rapid Response Squad ti won gbe iroyin naa sita je kó di mi mo pe lesekese t'okunrin naa ti be somi láwọn osise ori omi ti gbiyanju lati doola emi e.


Wọn jẹ kó yé wa pé seni akoroyin naa se bi eni to fe é tọ̀ sinu odo naa, ti ko sí fu ẹnikẹni lara, sugbon lojiji ni won lòó bẹ sodo, tawon oluranlowo ori omi náà sì tẹlé e.

A gbo pe won ti gbe okunrin naa lo sí tesan Èbúté Ero lati tẹsiwaju ìwádìí, bo tile je pe won ko fìdí è mule boya okunrin naa ti ku.

Agbenuso fún ajo to n ri sí isele pajawiri niluu Eko, iyen LASEMA, Ogbeni Kehinde Adebayo fìdí isele naa mule, oun gan an lo je ka mo pe akoroyin l'ọkunrin naa, ati pe oun ko nii daruko é sita.

Bẹẹ lọ so pe won ti ṣètò láti gbe oku é lo sí mosuari.

PÍN-IN KÁÀKIRI