ASIRI DANIEL TO RAN AWON ADIGUNJALE LOO JA SOOBU OGA E TU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 12, 2018

ASIRI DANIEL TO RAN AWON ADIGUNJALE LOO JA SOOBU OGA E TU

Kani gendekunrin eni odun mokanlelogbon (31), Michael Daniel ti won fesun kan pe o sagbateru awon adigunjale lati wa a ja soobu oga e mo pe asiri oun yoo pada tu ni, o see se ki ero buruku naa ma ti wa sokan e rara.

Gege ba a se gbo, ko tii ju ose meta ti won gba Daniel si soobu naa to wa ladugbo Asero niluu Abeokuta pe ko maa bawon bojuto soobu naa, to fi pawopo pelu awon adigunjale lati wa a ja soobu naa, ti won si ko ero amohunmaworan ti won n lo pe komputa, iyen monitor nibe salo.
Ogbon ojo osu kesan an to koja yi ni oga to gba Daniel si soobu, Arabinrin Titilayo Ero gba tesan olopaa lo lati loo foro naa to won leti, idi ni yii tawon olopaa fi ranse pe Daniel pe ko wa a so nnkan to mo nipa e.
AWIKONKO gbo pe se ni Daniel n koko paro fun won, sugbon ninu oro to tun n so lo je ki won fura sii pe o see se ko mo nipa e, idi ni yii ta a gbo pe won fi dana iya fun, to si jewo pe oun loun ran awon adigunjale naa lati wa a fo soobu naa.
Daniel so pe monito mejilelaadota (52) lawon ji ko, ati pe ore e oun kan to n je Smith Ajao lo sagbateru bi won se ta awon ero naa danu. Daniel lo lewaju awon olopaa lo sile Smith to wa ni Sango Ota, touj naa si jewo pe looto ni, ati pe awon ti ta a danu si Ikeja nibi ti won ti n ta orisirisi eto igbalode to fi mo komputa.
Nigba ti won de Ikeja, mejidinlaadota ni won ri gba pada ninu awon eru naa, ta a si gbo pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won tete loo foju awon odaran naa bale ejo.

PÍN-IN KÁÀKIRI