IGBEYAWO TOYIN AIMAKHU TUN FORI SANPON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 17, 2018

IGBEYAWO TOYIN AIMAKHU TUN FORI SANPON

SEGUN OKEOWO

Bi gbajumo osere tiata nni, tawon aye n gba ti e nidi ise tiata Yoruba ati oloyinbo nni, Toyin Abraham (Aimakhu) ko ba tete jade soro ara e, afaimo ko ma je pe se ni yoo di iya n dagbe titi ti yoo fi jade laye, lai ni ade ori.

Iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi tun je ko di mi mo pe aarin oun ati afesona e tuntun ti won jo n fera lati bii osu mefa seyin bayii tun ti daru.

Be o ba gbagbe, ni nnkan bi osu mefa seyin ni afesona e yi, eni ti won so pe ise agbejoro lo n se kenu ife si Toyin nita gbangba niwaju awon molebi Toyin pe ko je kawon maa fera, nibe lo si ti gba fun ti won n ba ere ife won lo.

Bo tile je pe a ko tii le fidi nnkan to tu aarin won ka, sugbon a gbo pe kii se pe won fi ija nla tuka, bi ko se pe aawo kekere kan la gbo pe o sele laarin won, ati pe awon mejeeji si n soro, sugbon won ko kan joo se ore fife mo ni.

PÍN-IN KÁÀKIRI