IYAALE ILE PA OKO E ATAWON OMO META DANU LOJO KAN SOSO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 3, 2018

IYAALE ILE PA OKO E ATAWON OMO META DANU LOJO KAN SOSO

...Bẹẹ lọ tun gba emi ara  e


K ayeefi niroyin naa sí n je  fawon ara agbegbe Vandeikya niluu Makurdi, ipinle Benue latari bi ìyáálé ilé to bi ọmọ meta fún oko e se deede pa oko è, to pa  awọn ọmọ métèèta, to sì tún pa ara e danu.
Bo tile je pe kii se awon araalu Makurdi niroyin naa sí n se ni kayeefi, gbogbo awọn to gbo nipa isele naa ti won so pe oro naa kii soju lasan, ọ lọwọ ayé ninu ni lohun tawon kan n so.


Titi dasiko ta ko iroyin yi tan la ko tíì moruko ìyáálé ilé náà, tabi eyikeyi ninu awọn ọmọ wọn, sugbon ta a gbo pe Nicholas Adetsav loruko oko naa n je, ati pe osise ijoba ibile, iyen Local Government Service Commission ni.

Ale ana Fraide la gbo pe wahala náà bẹ sílẹ laarin tokotaya yi, to sì di pe ìyáálé ilé náà gbe oro yi pari, to di pe o bere síi ba gbogbo dukia inu ile je.


Ere láwọn ara àdúgbò náà koko pe e, nigba ti won ri ìyáálé ilé yi to bere síi fo gilaasi moto oko e,to tun n pariwo kikan-kikan, bi won se n ni ko se sùúrù lo n yari mo won lowo.

Nigba tọrọ naa máa yiwo, se lobinrin naa wole, to sì tilekun mo oko e atawon ọmọ wọn sinu ile, lo ba gun oko e lórùn pa, bo se pa oko naa tan lo ba tun ki awọn ọmọ naa mole, to gun gbogbo won pa.


Bo se seyi tan loun naa ba tun gun ara e pa, leyin tawon araadugbo naa ko gbo ohun ẹnikẹni nínú won mo, ni won ja ilekun wole, ti won sì ba oku molebi naa nile.


Lesekese la gbo pe won ti lòó f'oro naa to awon olopaa leti, ki won to wa a gbe oku gbogbo won lo sí mosuari ijoba to wa nitosi. Bee la gbo pe awon olopaa sí n sewadi titi dasiko ta a ko iroyin yi tan.

Gbogbo awọn araadugbo la tun gbo pe oro naa ni won fi n s'orin ko bayii.

PÍN-IN KÁÀKIRI