O TAN O; AWỌN ỌBA YEWÁ LÁWỌN ṢETAN LÁTI SATILEYIN FÚN GBOYEGA ISIAKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 1, 2018

O TAN O; AWỌN ỌBA YEWÁ LÁWỌN ṢETAN LÁTI SATILEYIN FÚN GBOYEGA ISIAKA

Pẹlu ìdùnnú àti ayọ láwọn Ọba káàkiri ilẹ Yewa fi láwọn ti ṣetan lati satileyin fún adije sipo gomina ipinle Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC lọdun 2019, Ọmọba Gboyega Nasiru Isiaka, GNI.


Wọn ní láti lè jẹ ki ipinu awon wá sí imuse, paapaa lati gba ipò gomina tawon ti n le lati ogoji odun le diẹ seyin, a fi kawon fowosowopo satileyin fún Gboyega Isiaka to je adije to kun oju oṣuwọn ju lásìkò yí.

Ilu Ilaro lọrọ naa ti jade nibi ìpàdé awọn lobaloba, atawon olóyè ti won se, eyi ti Oba Kehinde Olugbenle to je Olú-Ilaro je alaga e, to waye lojo Wesde ànà.
N ibi ìpàdé naa ni won ti fẹnuko fa GNI kalẹ gẹgẹ bí ẹni tí wọn yóò tẹlé bi won ba fe é gba ipò náà tawon ti n le lodun to ti pẹ seyin.

Awọn Ọba aládé náà so pe gbogbo awon èèyàn naa ti ṣetan lati f'imo s'okan lati gbaruku ti GNI ninu idibo odun 2019 to n bọ lọnà yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI