OSISE IJOBA LU MAGUN LARA IYAWO ONIYAWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 20, 2018

OSISE IJOBA LU MAGUN LARA IYAWO ONIYAWO

Ariwo "ikunle abiyamo o" lo gba enu awon araadugbo Ebute Meta lowuro ana, iyen ojo Aje Monde nigba ti osise kansu, Rafiu Gbadamosi lu magun lara iyawo oniyawo, to si se bee gbona orun lo.


Ni nnkan bi aago mokanla aaro ni ariwo buruku yii so lagbegbe Cementary ni Ebute Meta, l’Ekoo nigba ti okunrin naa sadeede takiti lori obinrin ti won jo n se ere wamo-wamo, to si se bee dero orun.

Won ni o pe tawon mejeeji ti jo maa n sere wamowamo kiri, ti oko obinrin yii si maa n kilo fun iyawo e, ki kinni ohun too yiwo mo won lowo, nileetura kan ti won so pe won gbe ara won lo lagbegbe Evans Square, ti iyawo oniyawo si salo ni tie ni kete ti Rafiu ti je Olorun ni pe.

Ohun ta a gbo ni pe, ariwo ti iyawo e n pa ni kete tisele ohun waye ni pe, oun kilo fun oko oun to ko ye tele iyawo oniyawo kiri. Won lobinrin yii so pe, oko obinrin to gbe lo sile itura yii ti kilo fun un ko fi iyawo oun sile, sugbon ti oko e ko gbo.

Omo meta ni won so pe Rafiu bi, ijoba ibile kan ni Ebute Meta ni won so pe o ti n sise, bee ni won so pe o sese le ni omo ogoji odun ni, ati pe omo Ijebu Itele ni paapaa.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, oku okunrin yii si wa nile, lagbegbe Ebute Meta, bee lomobinrin ti won jo sere wamowamo yii ti salo ni tie.

A gbiyanju lati ba iyawo e soro, ero repete to pe le e lori ko je ki o le so ohunkohun.

Won ni okunrin naa si ni mama laye, ati pe ni nnkan bi ojo meloo kan seyin lo se akanse adura fun baba re to doloogbe ni nnkan bi ogun odun seyin.

PÍN-IN KÁÀKIRI