EYI LAṢIRI OWO TAWỌN OLOṢELU TI JI KO - EFCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 17, 2019

EYI LAṢIRI OWO TAWỌN OLOṢELU TI JI KO - EFCC

Bi ajọ to n ri si ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC ṣe gbe iye owo tawọn oloṣelu orileede Naijiria ti ji ko lati bi ọdun mejidinlogoji (38) sẹyin lawọn araalu bẹrẹ sii gbe awọn olori wọn ṣepe rabandẹ-rabandẹ.Image result for EFCC

Nigeria has recorded illicit financial outflows of $217.7bn in 38 years, specifically between 1970 and 2008, the Economic and Financial Crimes Commission, said in Abuja on Wednesday.

Image result for EFCC

Owo naa la gbọ pe ko din ni igba biliọnu dọla, iyẹn $217.7bn ni wọn lawọn oloṣelu ji ko larin ọdun 1970 si ọdun 2008. Ọjọ Wẹside ana ni ajọ EFCC kede ọrọ naa fawọn araalu nibi ipade gbogboogbo ọlọjọ kan ti ẹgbẹ awọn akọroyin ori ẹrọ ayelujara ṣe.

Ọgbẹni Tony Orilade to ṣoju alaga fidihẹ ajọ EFCC, Ibrahim Magu lo sọrọ naa jade lasiko toun naa gba ẹnu ọga ẹ sọrọ.

Tony sọ pe iwa jẹgudujẹra to n ṣelẹ lorileede yi ko ṣẹyin awọn eeyan kan, atawọn ẹgbẹ kan, to fi mọ awọn ileeṣẹ adani ati tijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI