GOMINA AMOSUN LOUN YOO TUN ỌNA IMALA ATI ILEWO ṢE KOUN TOO KURO N’IJỌBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 23, 2019

GOMINA AMOSUN LOUN YOO TUN ỌNA IMALA ATI ILEWO ṢE KOUN TOO KURO N’IJỌBA


Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti ṣeleri fawọn ti ṣeleri fawọn olugbe ilu Imala ati Ilewo, iyẹn lagbegbe Oke-Ogun nijọba ibilẹ Abẹokuta North wi pe oun yoo bawọn ṣe awọn ọna wọn koun too kuro nijọba.

Amosun ṣeleri yi lasiko to ṣe ipolongo lọ sagbegbe Imala laipẹ yi, o fidi ẹ mulẹ ọdun 1958, ki wọn too da ipinlẹ naa silẹ ni wọn ti ṣe ọna naa, ti ko si tii sijọba to ya si pẹlu bo ṣe bajẹ to.

Siwaju sii lo tẹnumọn ọn pe lootọ lo jẹ pe ko sijọba to le pari gbogbo iṣẹ lẹẹkan ṣoṣo bi ko ṣe pe itẹsiwaju ninu ijọba lo ṣe koko, ati pe oun mọ daju pe ijọba to n bọ lẹyin oun yoo tẹsiwaju awọn alakalẹ idagbasoke toun ti ṣeto silẹ.

Bakan naa lo rawọ ẹbẹ si wọn pe ki wọn tete lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko too lọ ati pe ki wọn yẹra fun iwa jagidijagan saaju ati lẹyin ọjọ idibo.

Ninu ọrọ ti ẹ, Ọmọla tiluu Imala, Ọba Moses Adelani dupẹ gidigidi lọwọ Gomina Amosun fun bo ṣe bawọn yanju wahala aala to wa laarin ilu naa ati ati ipinlẹ to sunmọn wọn, iyẹn Ọyọ.

Ninu iroyin min in, lati gbọ pe ko din lẹgbẹrun marun un oṣiṣẹ ijọba ni wọn ti pari idanwo aṣekagba fun tọdun 2016 si 2017, eyi ti wọn yoo fi gba igbega sipo tuntun.

Akọwe agba lẹka eto oṣiṣẹ (civil service commission), Arabinrin Amọpe Chokor lo fi ọrọ yi sita fawọn oniroyin lonii, ninu ọfiisi ẹ. O fidi ẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ naa yoo gba ipo giga latari bi wọn ba ṣe ṣe si ninu idanwo ti wọn ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI