Alase ati oludari ile itura IBD ati IBD impex Alhaji Ibrahim Dende Egungbohun ti gbe osuba kare fun Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun fawon akanse ise to lo kaakiri ipinle naa ati agbegbe e.
Bo se gbe osuba fun Gomina Amosun bee naa lo ro awon olugbe ipinle Ogun lati je ki alaafia joba laarin won tori eyi nikan lo le je ki itesiwaju ba ipinle Ogun ti yoo si tun ran won lowo lati jegbadun idagbasoke ti ijoba Ibikunle Amosun n mu ba ipinle naa.
Alhaji Egungbohun so oro yi ninu ofiisi e to wa nilu Ilaro lasiko to n fi ebun odun tore fawon akoroyin.
O salaye pe ifowosowopo ati isotito nikan ni awon omo ipinle Ogun le fi ran Gomina Amosun lowo nitori awon idojuko ti Gomina n ni lori eto oro aje ati oro Oselu ipinle Ogun.
Dende se alaye siwaju pe bo tile je pe ipo oro aje orileede yi ko fi bee rosomu, sibe Gomina Amosun sa gbogbo agbara e lati rii pe idagbasoke ba ipinle naa.
Bee ni o gba awon olugbe ipinle Ogun lamoran lati ni igbagbo ninu ijoba Amosun tori eyi nikan lo le tun ran ijoba lowo lati se asepari ise to dawole.
Egungbohun gboriyin fun ijoba ipinle Ogun labe idari Gomina Amosun fun sise awon ise idagbasoke jakejado ipinle yi, tori eyi wa lara ohun ti o n fa awon ti won maa n dase sile wa si ipinle Ogun.
Beeni IBD ro awon akoroyin lati ma se je ki irewesi mu won lenu ise won lati maa gbe iroyin ohun to ba sele jade lasiko tori awon nikan ni awon araalu gbe ara le.
No comments:
Post a Comment