ILE ẸJỌ TUN PADA LẸYIN LADI ADEBUTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 17, 2019

ILE ẸJỌ TUN PADA LẸYIN LADI ADEBUTU

Nigba to yẹ ki oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP n'Ipinle Ogun, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, maa yo pe wahala ti Sẹnetọ Buruji Kaṣamu n ba oun fa ti fẹ ẹ di ohun igbagbe, ile ẹjọ giga niluu Abuja tun ti da wahala si i lagbada bayii.


Ile ẹjọ giga tiluu Abuja ni bi wọn ṣe yan an ni oludije ko tọna rara
.
Funra ẹ naa lo gbe ẹjọ lọ si kọọtu, tori o fẹ ki wọn ba oun gba Kaṣamu segbẹ kan.

Ohun to wa pani lẹrin diẹ ni pe ni nnkan bii ọsẹ kan si ọjọ idajọ yii ni Kaṣamu n sọ pe ki awọn darapọ lọna alaafia ninu ẹgbẹ PDP n'Ipinle naa.

Koda, iroyin ko tan kanle pe o so pe oun setan lati gba Adebutu laye ki o je oludije ni.

Sugbon ojo keta loun naa tun ni oun ko so bee, oun kan n soro irepo ni.

Lati: IROYIN OWURỌ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI