JẸLILI TO FIPA BA IYA ARUGBO SUN FOJU BA ILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 17, 2019

JẸLILI TO FIPA BA IYA ARUGBO SUN FOJU BA ILE ẸJỌ

Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi, epe buruku lawọn eeyan kaakiri agbaye ṣi n fi baale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji, Jẹlili Lawal ṣẹ latari bo ṣe fipa ba iya arugbo ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78) sun, to si fa iya naa nidi ya pẹrẹpẹrẹ.

Ọjọ Wẹside ana lawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko foju jẹlili ti wọn niṣẹ awakọ lo n ṣe ba ile ẹjọ. Ọjọ kinni-in oṣu yi la gbọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko foju Jẹlili han fawọn akọroyin ipinlẹ naa.
Image result for Police arraign bus driver for raping 78-year-old
AWIKONKO gbọ pe iya arugbo naa ni ko mọ ibi to n lọ, eyi lo fa a to fi rawọ ẹbẹ si Jẹlili lai mọ pe erongba buruku ti wa lọkan lati ṣe. Wọn ni nigba ti Jẹlili gbe iya naa de ibi to n lọ, kaka ko ja a ju silẹ, ṣe lo gbe e wọnu ile akọku kan, to si wọ iya arugbo naa wọle, ko too fipa ba a sun nibẹ lai wo ọjọ ori ẹ.Bo tilẹ jẹ pe Jẹlili sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn ta a gbọ pe Adajọ ile ẹjọ Majisireeti naa, Arabinrin B.O Ọṣunsanmi sọ fun un pe ko tọju alaye e nitori pe ọdaju eeyan ni.

Adajọ naa wa a paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣi lọ ọ fi Jẹlili pamọ si ọgba Kirikiri titi di ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun yi ti igbẹjọ min-in yoo waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI