Kelechi Okwuchi |
Kelechi, ẹni kan soso tó yè
nínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú náà tó já lọ́dún 2005, ló fi ohùn rẹ̀ dábírà nínú
ìdíje náà pẹ̀lú bí ó ṣe kọ ọ̀kan nínú àwọn orin Collin Scott èyí tí ó sì mú u tẹ̀síwájú
dé ìpele náà.
Ọjọ kẹfà Oṣù kẹfà, ọdún 2017
ló di ẹni mímọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìdíje; America Got Talent nígbà tí ó kọ ọ̀kan
nínú àwọn orin Ed Sheeran lẹ́yìí tí ó jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn olùdánwò fún
ìdíje náà.
Nígbà tó ń fi ìdùnnú rẹ̀ hàn
lórí ìkànnì ayélujára, Twitter, Kelechi dúpẹ́ lọ́wọ Ọlọ́run fún àṣeyorí tó ṣe
nínú ìdíje náà.
Gbogbo ènìyàn, pàápàá àwọn
olólùfẹ́ ìdíje náà ló fi ìdùnnú wọn hàn sí
àṣeyọrí rẹ̀ nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi akínkajú àti
aláforítì ẹ̀dá.
No comments:
Post a Comment