KÒ SÍ OHUN TÓ KÀN WÁ PẸ̀LÚ ẸNI TÓ BÁ JÁWÉ OLÚBORI NÍNÚ ÈTÒ ÌDÌBÒ ỌDÚN 2019 – ÀJỌ EU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 22, 2019

KÒ SÍ OHUN TÓ KÀN WÁ PẸ̀LÚ ẸNI TÓ BÁ JÁWÉ OLÚBORI NÍNÚ ÈTÒ ÌDÌBÒ ỌDÚN 2019 – ÀJỌ EU

Ìgbìmọ̀ tó ń wòye bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ sí nílẹ̀ wa, Nàíjíríà èyí tó wà lábẹ́ Àjọ Iṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúròòpù (EU) ti sọ ọ di mímọ̀ pé àwọn kò ní ìfẹ́ nínúu ríri i pé adíje tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló jáwé olúborí nínúu ìdìbò àpapọ̀ tó ń bọ̀.

Alága ìgbìmọ̀ náà, Maria Arena ló sọ̀rọ̀ yìí fún àwọn akọròyìn ní ìlú Abuja pẹ̀lú àlàyé pé àfojúsùn àjọ náà ni láti ní àkọsílẹ̀ bí ohun gbogbo ṣe lọ sí nínú ètò ìdìbò náà.


Ó ní kò sí ohun tó kan ìgbìmọ̀ náà pẹ̀lú èsì ìdìbọ̀, adíje tí ó wọlé tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú tó jáwé olúborí bíkòṣe pe àjọ náà rán wọn láti rí i dájú pé wọ́n wòye bí ètò ìdìbò náà ṣe lọ ní ìrọ̀wọ́ àti ìrọṣẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbìmọ̀ náà kò wà láti ṣègbè lẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kankan ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbìmọ̀ tó wà lábẹ́ ìdarí àjọ EU èyí tó dúró lóri ìfinimọniyànse àti iṣòótọ́.

Arena wá gba àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú pàápàá àjọ tó ń ṣètò ìdìbò nílẹ̀ wa, INEC lámọ̀ràn láti dúró lórí òtítọ́ àti òdodo ní gbogbo ìpele ètò ìdìbò náà kì ò ba lè kẹ́ṣẹjárí pẹ̀lú àlàyé pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni yóò mú àwọn ará ìlú ní ìgbẹkàlé nínú iṣẹ́ wọn.

Ó ní ètò ìdìbò náà ni ó fún gbogbo ọmọ Nàíjíríà ní àǹfàní láti ró ètò iṣèjọba àwarawa lágbára síi ju ti àtẹyìnwá lọ nítorí náà ni kí àwọn tórọ̀ kàn lórí ètò ìdìbò náà pàápàá àjọ INEC àti àwọn elétò àbò ṣíṣe wọn bíi iṣẹ́ láti mú ìdìbò náà lọ ní àlááfíà.
   

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI