O MA ṢE O: FIJILANTE PA SỌJA DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 25, 2019

O MA ṢE O: FIJILANTE PA SỌJA DANU


Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi ni wahala ṣi fi n ṣẹlẹ lagbegbe Ozubulu nipinlẹ Amanbra, latari bi wọn ṣe lawọn oṣiṣẹ eleto aabo, iyẹn awọn Ozubulu Vigilante Service ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn akẹkọọ ileewe Ṣọja tipinlẹ Kadanu.

Ohun ta a gbọ ni pe tẹgbọn taburo kan ni wọn ni gbọnmisi-omi-o-to lọjọ Wẹside to kọja yi, to si jẹ pe ija naa pọ gidi, afigba ti wọn lawọn agbaagba ladugbọ naa, to fi mọ awọn oloye ṣẹṣẹ bawọn da sii.

Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa la gbọ lara awọn to wa nitosi ti ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ Fijilante yi lati wa a da sii, ki wọn si yanju ẹ fun wọn, ṣugbọn ki wọn too de, ọrọ ti niyanju.

 

Bo ṣe maa di nnkan bi aago meji oru la gbọ pe awọn Fijilante yi tun lọ sile ọdọmọkunrin yi, ẹni ti wọn lo o wa lẹnu isinmi ranpẹ, eyi ti wọn fun wọn nileewe wọn, iyẹn ileewe tawọn ologun (Nigerian Army School) to wa ni Kaduna.

Ẹẹmẹta ọtọọtọ la gbọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ Fijilante yi yinbọn fun un, asiko ti wọn n gbe e lọ si ọsibitu lati doola ẹmi ẹ lo jade laye.

Lẹsẹkẹsẹ la gbo pe awọn ọdọ adugbo ti ko ara wọn lọ si ọfiisi awọn Fijilante naa, ti wọn si lọọ dana sun mọto ati ọfiisi wọn pẹluu.

Ni bayii, a gbọ pe awọn ọlọpaa ti da si iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI