OGUN 2019: IYADUNNI, OBINRIN AKỌKỌ TI YOO DI GOMINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 30, 2019

OGUN 2019: IYADUNNI, OBINRIN AKỌKỌ TI YOO DI GOMINA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Bi wọn ba n sọ nipa awọn abiyamọ tootọ, to ko awọn eeyan mọra, to n ṣaanu fawọn alaini, paapaa awọn to ni ipenija ara, odu ni Oloye Arabinrin Jackie Adunni Kassim, kii ṣaimọ foloko.

Bo ṣe n ṣe fun onile, bẹẹ lo n ṣe fun alejo, ko da a, awọn to sunmọn ọn ko ye e royin iwa rere ẹ laarin awujọ, idi ni yii ta a gbọ pe awọn agbaagbaa laarin ilu fi panupọ pe ki wọn yan Oloye Arabinrin Adunni Kassim gẹgẹ bi Iyalode ilu Igbore, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Latigba ti Arabinrin Adunni Kassim ti di Iyalode ilu Igbore ni nnkan bi ọdun meloo kan sẹyin, ko sẹni to royin ẹ laburu, ko si sẹni ti kii gbe oṣuba kare fun un nitori ti wọn lo n fi iwa olori han, ti iwa ọmọluabi ara ẹ naa ko ye e pokiki ẹ kaakiri.

Arabinrin Adunni Kassim to tun jẹ Dokita, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si IYADUNNI pẹlu iwadii ti a ṣe la ti gbọ pe awọn agbaagba nipinlẹ Ogun ni wọn fọwọ sọya lori ẹ pe ko jade fun ipo gomina ipinlẹ Ogun, ko si lọọ ja fun ẹtọ awọn araalu.

Lọjọ Mọnde to kọja yi ni Iyadunni lọ siluu Ọta, nijọba ibilẹ Ọta lati lọọ bawọn eeyan sọrọ nipa ipinu ẹ lati jade du ipo naa, labẹ ẹgbẹ oṣelu United Democratic Party, UDP, ẹgbẹ to n ṣe agbelarugẹ iṣọkan ati ifẹ laarin ilu.

Lọjọ Mọnde naa, ẹsẹ ko gbero lori papa ti wọn lo nitori pe ṣe ni gbogbo agbegbe naa kun fọnfọn, tawọn eeyan si n sọ ohun rere nipa Arabinrin naa, ko da a, tawọn kan n sọ pe Iyadunni nikan lo le ṣe nnkan tawọn araalu n fẹ fun wọn.

Bi a ko ba parọ, igba akọkọ lọjọ Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọ oṣu kinni ọdun 2019 ti aṣojukọroyin AWIKONKO, Bọsun Ọlanrewaju yoo ri ibi tawọn alaabọ ara ti pọ to bẹẹ, ko ti ẹ yeeyan boya wọn ni ẹgbẹ ni, ṣugbọn ohun ti gbogbo wọn n sọ ni pe awọn ko le gbagbe ohun rere ti Iyadunni ti ṣe fawọn, tawọn si ṣetan lati gbaruku ti obinrin naa gẹgẹ bi abiyamọ to n gbọ igbe awọn eeyan.

Nigba toun funra ẹ n sọrọ, Oloye-Dokita-Arabinrin Jackie Adunni sọ pe ko si nnkan meji to mu koun gba lati jade dupo gomina bi ko ṣe awọn ipinu rere toun ni fawọn eeyan, paapaa awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun.

O ṣeleri pe gẹgẹ bi obinrin, oun ko nii ṣoju-ṣaaju lati ṣiṣẹ idagbasoke siluu kan ṣo’so bii tijọba to wa nita lonii, o ni gbogbo agbegbe patapata to wa nipinlẹ Ogun loun yoo ṣiṣẹ idagbasoke de, toun yoo si ṣe awọn ọna igberiko kaakiri.

O ni lara awọn nnkan toun ni lọkan lati ṣe ni Eto Ilera to peye nibi tawọn to ba ni ipenija ara yoo ti jẹ anfaani alailẹgbẹ, ati pe awọn to ba n ṣaisan gan an ko nilo lati da ara wọn laamu mọ nipa lilọ kaakiri lai ri itọju, nitori pe gbogbo ọsibitu loun yoo tun ṣe, toun yoo si ro awọn oṣiṣẹ lagbara.

Eto Ẹkọ alailẹgbẹ ni ipinu keji to loun ni lọkan lati ṣe, nitori pe kii ṣe ahesọ wipe eto ẹkọ ipinlẹ Ogun ti dorikodo, to si nilo keeyan tete mojuto. Jackie Adunni tẹnumọ ọn pe ibanujẹ ọkanlo maa n jẹ foun nigba toun ba ri bawọn ileewe to jẹ tijọna ṣe ri, to jẹ pe ilẹẹlẹ lawọn akẹkọọ ti n kẹkọọ, ṣugbọn gbogbo ẹ ni yoo yatọ lasiko ijọba toun.

Eto Aabo to wa larọwọto jẹ ọkan pataki nnkan toun fẹẹ ṣe. Agbegbe to ṣee mu yangan jẹ Iyadunni logun pupọ, ti yoo si mu kawọn eeyan maa gbe ninu ilera to peye.


Atunṣe gbogbo ibi igbafẹ, igbelarugẹ aṣa atawọn nnkan idaraya to ṣee mu yangan, idagbasoke Iṣe Agbẹ, ati iṣejọba ti ko lafiwe, iṣejọba ti kii fi nnkan pamọ fawọn araalu wa lara eto ti abiyamọ naa n gbe bọ wa fawọn araalu. O wa a ku sawọn araalu lọwọ lati yan laari igbekun ati itusilẹ. O ku sawọn araalu lọwọ lati yan adari gidi, ki wọn si dẹkun lati maa dibo fun awọn oloṣelu ẹlẹtanjẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI