WỌN TI FI OFIN DE TẸTẸ TITA LORILEEDE UGANDA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 23, 2019

WỌN TI FI OFIN DE TẸTẸ TITA LORILEEDE UGANDA

Aarẹ orileede Uganda, Yoweri Museveni ti sọ pe tẹtẹ tita lorileede naa ti di eewọ fun gbogbo awọn to n ta a patapata, wọn ko si gbọdọ kofiri awọn agbegbe ti wọn ti n ta a mọ titi ti yoo fi gbe ijọba silẹ.

Kii ṣe pe Aare Yoweri fofin de tẹtẹ tita nikan, o tun paṣẹ pe gbogbo awọn ileeṣẹ ti wọn ti gba iwe aṣẹ ni ki wọn loo fi pamo, tabi pe ki wọn lọọ fa a ya danu, o tun sọ pe awọn ileeṣẹ tuntun to ba fẹ ẹ gba iwe aṣẹ ni wọn ko lanfaani lati gba a mọ, bẹẹ lo tun lawọn to ti gba iwe aṣẹ ni wọn ko lanfaani lati tun un ṣe.

Gẹgẹ bi Minisita fọrọ eto iṣuna, Ọgbẹni David Bahati ṣe fi iroyin naa sita lọjọ Sande to kọja yi lasiko to n sọrọ nibi isin onigbagbọ to ṣe ni Rugarama Hill ni western Kabale, o ni Aarẹ orileede naa jẹ ko di mi mọ pe tẹtẹ tita naa ti gbe ọkan awọn ọdọ orileede naa kuro ninu awọn nnkan to le mu ki wọn ronu idagbasoke.

O wa a ni kawọn ṣọọṣi ti wọn ti n gbadura pe ki Ọlọrun ba wọn pa ogun tẹtẹ naa run ni wọn lọ maa kọ orin aleluya bayii, nitori pe adura wọn ti gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI