AFCON U-20: FLYING EAGLES FI ỌWỌ́ TÓ DÁA BẸ̀RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 3, 2019

AFCON U-20: FLYING EAGLES FI ỌWỌ́ TÓ DÁA BẸ̀RẸ̀


Ikọ̀ flying Eagles ilẹ̀ wa lánàá Ọjọ́ Àbámẹ́ta fi ìyà àmì ayò méjì jẹ Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Ilẹ̀ Burundi láti fi síde ìpolongo wọn nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ ti ilẹ̀ Afíríkà èyí tọ́jọ́ orí wọn kóju ogún lọ.

Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù ọjẹ̀wẹ́wẹ́ ilẹ̀ wa náà gbá góòlù méjì náà wọlé ní abála kejì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà èyí tí ó sì ti mú wọn léwájú nínú ìsọ̀rí A tí wọ́n wà.

Nazifi Yahaya àti Effiom Maxwell ló mú Ikọ̀ Flying Eagles jáwé olúborí nígbà tí wọ́n mi àwọ̀n ní ìsẹ̀jú arùndínlọ́gọta àti ọgọ́rin ìfẹṣẹ̀wọnṣẹ̀ náà.

Ikọ̀ ilẹ̀ South Africa tí wọ́n gbá àmì ayò kọ̀ọ̀kàn pẹ̀lú Ikọ̀ Niger, ni Flying Eagles  yóò gbéná wojú nínú ìfẹṣẹ̀wọnṣẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ti wọn yóò gbá lỌ́jọ́rú tó ń bọ̀.

Ṣáájú àsìkò yìí ni Akọnimọ̀ọ́gbá fún Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Àgbà ilẹ̀ wa Super Eagles, Gernot Rohr ti pe àwọn agbábọ́ọ̀lù ọjẹ̀wẹ́wẹ́ náà láti sa gbogbo ipá wọn láti ṣàseyọrí nínú ìdíje náà.

Ó ní òun yóò wà níbi ìdíje náà láti máa wo àwọn agbábọ́ọ̀lù tó ṣe dáadáa èyí tí yóò sì mú wọ Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Àgbà ilẹ̀ wa, Super Eagles.

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù mẹ́rin tó bá dé ipele tó kángun sí àṣekágbá ni yóò ṣojú ilẹ̀ Afíríkà nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbàyé fún àwọn tọ́jọ́ orí wọn kò ju ogún lọ èyí tí yóò wáyé ní Orílẹ̀-Èdè Poland láàárín ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù karùn-ún sí ọjọ́ kẹẹdọ́gún oṣù kẹfà, ọdún yìí.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI