EKITI: WỌN LAWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OṢELU APC TO BA ṢIṢẸ FUN PDP YOO FẸNU FẸRA BI ABẸBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 2, 2019

EKITI: WỌN LAWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OṢELU APC TO BA ṢIṢẸ FUN PDP YOO FẸNU FẸRA BI ABẸBẸ

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afaimọ ki ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti ma padanu ibo ọdun 2019 to n bọ yi sọwọ ẹgbẹ alatako wọn, iyẹn ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa, paapaa awọn to tun jẹ oloye ninu ẹgbẹ naa ṣiṣẹ labẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ati pe lara awọn ti wọn yan lati ṣabojuto eto idibo ipinlẹ naa n ji awọn owo to n wọle ko, ti wọn ko si fi jiṣẹ sawọn ibi to yẹ ki wọn fi jiṣẹ si, ta a si gbọ pe ọpọ igba lawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa ti kilọ fun wọn.

Bawọn kan ṣe n sọ pe awọn ti wọn yan naa n ṣiṣẹ fawọn ẹgbẹ alatako ni, tawọn kan si n sọ pe ifẹ ọkan wọn ati pe nitori atijẹ ti wọn ni wọn ṣe wa a gba iṣẹ naa, bẹẹ lawọn min in sọ pe ki wọn tete yọ wọn kuro, ki wọn ma baa ba ẹgbẹ naa jẹ, paapaa ki wọn ma jẹ kawọn padanu ninu idibo to n bọ lọna yi.

Lọjọ Fraide ana ni igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi gbawọn eeyan naa lamọnran pe ki wọn ye e fi ifẹ ọkan wọn ṣiṣẹ fun ẹgbẹ, bi ko ṣe pe ki wọn maa lo agbekalẹ ẹgbẹ lati fi tukọ oṣelu, ki wọn ma baa padanu.

Ẹgbẹyẹmi to sọrọ yi lasiko ti wọn gbe ọpa asṣẹ fawọn igbimọ ti wọn yan lati dari eto idibo laaringbungbun ipinle Ekiti, iyẹn Ekiti Centra Senetorial campaign.

Igbakeji gomina naa tun sọ pe oun mọ pe awọn kan ninu ẹgbẹ naa ṣetan lati dalẹ ẹgbẹ, kiru awọn bẹẹ si tete fi ẹgbẹ silẹ ko too pẹ ju bi wọn ba mọ pe awọn ko le ṣiṣẹ gidi fẹgbẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, nigba toun naa n sọrọ, alaga ẹgbẹ oṣelu naa nipinle Ekiti, Ọgbẹni Paul Ọmọtọṣọ gbawọn oloye tuntun naa lamọnran pe ki wọn tubọ maa ṣe idanilẹkọọ fawọn olodibo to wa lagbegbe wọn, ki wọn le mọ awọn nnkan to ba yẹ nipa idibo to wọle tan yi, lati le dẹkun awọn ibo to maa n ṣofo danu.

O ni ninu idibo gomina to kọja lọ, ko din lẹgbẹrun mejidinlogun ibo tawọn padanu latari ailoye to fawọn oludibo, ati pe wọn ko dibo naa daadaa bo ṣe yẹ ki wọn di (void votes), to mu ki aaye kekere ṣi silẹ lati bori.

Bakan naa lo tun sọ pe ẹni to ba n gbiyanju lati dalẹ ẹgbẹ naa nipa lilo awọn ohun elo ẹgbẹ fi ṣiṣẹ ara ẹ, iru ẹni bẹẹ yoo fi oṣelu pitan lorileede yi, paapaa bi wọn ba jẹ ki ẹgbẹ oṣelu PDP rọwọ mu, nitori pe awọn ko nii gba fun ẹgbẹ PDP lati rọwọ, ati pe kawọn ọmọ ẹgbẹ bọwọ fun ẹgbẹ naa.

Bakan naa lo tun sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni aaye kankan mọ nipinlẹ naa, nitori naa, ọmọ ẹgbẹ oṣelu to ba dalẹ ẹgbẹ yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ.

Awọn oloye tuntun yi la gbọ pe wọn yoo ṣiṣẹ kaakiri wọọdu mẹtadinlọgọta to wa laaringbungbun Ekiti fun ibo Aarẹ Buhari ati ti adije sipo sẹnetọ, Ọpẹyẹmi Bamidele, to fi mọ awọn bii adije sipo ile igbimọ aṣoju-ṣofin kinni ati ikeji, Ṣọla Fatọba ati Wunmi Ogunlọla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI