EYI LAWỌN NNKAN IJA OLORO TI WỌN FẸẸ FI JI IBO GBE NI KANO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 16, 2019

EYI LAWỌN NNKAN IJA OLORO TI WỌN FẸẸ FI JI IBO GBE NI KANO

Pupọ ninu awọn to ri ohun ija oloro rẹpẹtẹ tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano gba lọwọ awọn tọọgi ti wọn ṣetan lati fi dabaru ibo to fẹẹ waye lonii Satide ni wọn la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko le paa de.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn kan ti wọn sakiyesi awọn ọdaran yi ni wọn ta awọn ọlọpaa lolobo, tawọn naa ko si fọrọmfalẹ rara, ki wọn to lọọ koju wọn, iyalẹnu lo si jẹ pe nibi ti wọn ti n palẹmo lati pin awọn ohun ija oloro na funra wọn laṣiri wọn ti tu.
 


Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni Oogun abẹnugọngọ, aake, igi, irin, taba, oogun oloro ti wọn n pe ni Kwaya, ada loriṣiriṣi, solition, suck and die, abẹrẹ potwin, Valiu 5, Diazaperm ati bẹẹ bẹẹ lọ.




Awọn tọọgi ti ko din lẹẹdẹgbẹta (500) la gbọ pe ọwọ tẹ ta a si gbọ pe ọsẹ to n bọ ni wọn yoo foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI