GOMINA AJIMỌBI FA IBINU YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 26, 2019

GOMINA AJIMỌBI FA IBINU YỌ

Gomina Abiọla Ajimọbi tipinlẹ Ọyọ ti fesi si ifidirẹmi rẹ ninu esi ibo ile aṣofin agba to waye lọjọ Abamẹta.

Ninu esi rẹ, o dupẹ lọdọ ara ipinlẹ Ọyọ ṣugbọn ko ki akẹgbẹ rẹ to jawe olubori ku oriire aṣeyọri rẹ.

Ikini yi la ri ninu fọnran fidio kan ti o ti sọ fun oniroyin Dele Momodu pe inu ohun dun si bi ibo naa ti ṣe lọ.

Ẹka ẹrọ ayelujara ti Instagram ni fọnran naa wa nibi ti Gomina Ajimobi ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani ti ohun ni lati sin awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

O ka awọn aṣeyọri rẹ lori idibo to n lọ lọwọ ti o si ni ohun ko ipa ribi ribi lati ri wi pe ipinlẹ Ọyọ dibo fun Aarẹ Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ oṣelu APC.

Toun ti bi o ti ṣe ni inu ohun dun ga an lori ibo naa, oni ohun ko ni i ki akẹgbẹ ohun to jawe olubori aya fii ti ohun ba ri aridaju pe ko si mago-mago ninu idibo.

APC Oyo ti saaju fapá jánú lórì ìfìdírẹmi Ajimọbi.

Ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọyọ ti kọwe ẹhonu si ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, nipa awọn aisedeede to sọ pe o suyọ lasiko eto idibo sile asofin agba lẹkun guusu ipinlẹ Ọyọ.

Ẹgbẹ oselu APC salaye pe, awọn aisedeede naa lo sokunfa bi gomina Abiola Ajimọbi se fidirẹmi ninu ibo naa, ti wọn si ti fi iwe ẹhonu naa pẹlu abọ iwadi awọn ọlọpa silẹ fun ajọ INEC.

Ọmọwe Azeez Ọlatunde, tii se oludari fun eto iwadi ati aato fẹgbẹ APC, lo gbe iwe ẹhonu naa kalẹ lọjọ Aje, lẹyin ti ajọ INEC kede Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo bori ninu ibo sile asofin agba naa.

Saaju ni Ọmọwe Azeez Ọlatunde , tii se asoju ẹgbẹ oselu APC ni ibudo ti wọn ti n ka ibo sile asofin agba naa, ti kọkọ fapa janu ni ibudo ti wọn ti n ka ibo naa pe, wọn ko gbọdọ kede esi ibo ọhun.

Ọlatunde ni awọn janduku kan lo wa da ibo ru ni wọọdu mẹta kan lẹkun idibo ọhun, eyi to mu ki awọn ibo ti wọn padanu pọ pupọ.

Sugbọn osisẹ ajọ eleto idibo, to n se kokari esi ibo naa, Ọjọgbọn Wọle Akinsọla ni ki asoju ẹgbẹ oselu APC ko gbogbo ẹhonu to ba ni lọ si olu ileesẹ ajọ eleto idibo, to si kede esi ibo naa.

Ọmọwe Kọla Balogun si lo jawe olubori ninu ibo naa, ti Senetọ Abiọla Ajimọbi si se ipo keji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI