Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Pupọ ninu awọn tọrọ naa ti ta si leti ni wọn ti n foju sọna lati mọ igba ti iwe iroyin Yoruba tuntun nni ti wọn pe orukọ ẹ ni AṢEJERE yoo jade sita.
Ni bayii, ohun ta a gbọ ni pe
ọsẹ to n bọ, iyẹn lẹyin idibo apapọ orileede yi ni yoo jade sita, ti yoo si mi
gbogbo ilu titi latari awọn ọna ara-ọtọ ti wọn fẹẹ maa fi gbe iwe iroyin naa
jade.
Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, ori
okoowo ati eto ọrọ aje ni iwe iroyin naa yoo da lori, ti yoo si mu anfaani nla
ba gbogbo awọn ọlọja ati ileeṣẹ nla-nla, to fi mo kekeeke.
Nigba to n gbe iroyin naa si wa
leti laipẹ yi, Olootu fidihẹ fun iwe iroyin naa, Arabinrin Sinmisọla Ajadi sọ
pe ileeṣẹ Hebron Media Concepts ni yoo maa gbe iwe iryoin AṢEJERE naa jade, ti
yoo si da lori eto ọrọ aje nikan lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje orileede yi.
O ni ko si nnkan meji to jẹ
kawọn pinu lati da iwe iroyin naa silẹ bi ko ṣe pe lati ran awọn ileeṣẹ perete
ati nla, awọn ọlọja nla ati pẹẹpẹẹpẹ lọwọ ki eto ọrọ aje wọn le tubọ gun oke
agba siwaju sii.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ
pe lati ma jẹ ki ọrọ ajọ UNICEF ti wọn sọ pe bi yoo ba fi di ọdun 2025, ọpọ ede
abinibi yoo dohun igbagbe wa si imuṣẹ lo mu erongba naa wa.
No comments:
Post a Comment