LẸYIN TO PADANU, GOMINA AJIMỌBI BU SẸKUN BI ỌMỌ TUNTUN JOJOLO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 25, 2019

LẸYIN TO PADANU, GOMINA AJIMỌBI BU SẸKUN BI ỌMỌ TUNTUN JOJOLO

...lawọn APC ba lawọn ko nii gba 

Abiola Ajimọbi

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Bi ajọ eleto idibo ṣe kede Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo jawe olubori nibi idibo awọn aṣofin agba niluu Abuja, eyi to waye niluu Ibadan lọjọ Satide to kọja yi, loju ẹsẹ ni Gomina Abiọla Ajimọbi ti bu sẹkun bi ọmọ tuntun jojolo.

Ṣugbọn ṣa, ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ti kọwe ẹhonu si ajọ eleto idibo orileede Naijiria, INEC, nipa awọn aiṣedeede ti wọn loo jẹyọ lasiko eto idibo sile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja lẹkun guusu ipinlẹ Ọyọ.

Ẹgbẹ oṣelu APC ṣalaye pe, awọn aiṣedeede naa lo ṣokunfa bi Gomina Abiọla Ajimọbi ṣe fidirẹmi ninu ibo naa, ti wọn si ti fi iwe ẹhonu naa pẹlu abọ iwadi awọn ọlọpaa silẹ fun ajọ INEC.

Ọmọwe Azeez Ọlatunde, to jẹ oludari fun eto iwadi ati aato fẹgbẹ APC, lo gbe iwe ẹhonu naa kalẹ lọjọ Aje onii, lẹyin ti ajọ INEC kede Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo bori ninu ibo sile igbimọ aṣofin agba naa.

Ṣaaju asiko yi ni Ọmọwe Azeez Ọlatunde, tii ṣe aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ni ibudo ti wọn ti n ka ibo awọn aṣofin agba naa, ti kọkọ fapa janu ni ibudo ti wọn ti n ka ibo naa pe, wọn ko gbọdọ kede esi ibo ọhun.

Ọlatunde ni awọn janduku kan lo wa a da ibo ru ni wọọdu mẹta kan lẹkun idibo ọhun, eyi to mu ki awọn ibo ti wọn padanu pọ pupọ.

Ṣugbọn oṣisẹ ajọ eleto idibo, to n ṣe kokaari esi ibo naa, Ọjọgbọn Wọle Akinsọla ni ki aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ko gbogbo ẹhonu to ba ni lọ si olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo, to si kede esi ibo naa.

Ọmọwe Kọla Balogun si lo jawe olubori ninu ibo naa, ti Senetọ Abiọla Ajimọbi si se ipo keji.

Ohun tawọn kan n sọ bayii ni pe kin ni Gomina Ajimọbi tun n wa kaakiri lẹyin to ti figba kan ri sọ ọ nita gbangba pe oun ko tun nilo ipo kankan mọ lẹyin Gomina ẹlẹẹkeji ti wọn foun lanfaani ẹ yi.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI