OṢELU NAIJIRIA KO GBA GIDIGBO - ỌMỌBA ỌRUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 4, 2019

OṢELU NAIJIRIA KO GBA GIDIGBO - ỌMỌBA ỌRUN

Image may contain: 1 person, smiling, text 
Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi a ba n sọ nipa awọn ti Ọlọrun fi iṣẹ orin ran, nipa awọn ti Aṣẹda fun ni ọgbọn, imọ ati oye nipa iṣẹ olukọni, odu ni Ọgbẹni Olufẹmi Ọrunṣọla, ẹni tawọn olofẹẹ mọ si Ọmọba Ọrun, kii ṣai mọ foloko. Bo ṣe n ṣiṣẹ olukọni nile ẹkọ giga gbogboniṣe, bẹẹ lo n kọrin, to tun dawọn eeyan laraya lode ariya, paapaa ai le mojukuro ni nidi iṣẹ tiata. Gbogbo orin ti Ọmọba Ọrun n kọ lo kun fun ọgbọn, tawọn ọjọgbọn kaakiri si n gbe oṣuba kare fun un nitori pe ko si aṣadanu ninu ẹ. Laipẹ yi ni gbajumọ olukọni naa gbe ẹyọ orin ti a mọ si singles meji jade sita, eyi to pe ni ‘Ko Gba Gidigbo’, ati 'Ibo Ifẹ' orin to kọ nibamu pẹlu eto oṣelu orileede Naijiria lasiko yi, ninu ẹ lo si ti fi gbawọn eeyan nimọnran, paapaa awọn oloṣelu pe ki wọn rọra ṣe, mitori pe oṣelu ko gbọdọ jẹ eyi ti yoo gba jagidijagan.

Lopin ọsẹ to kọja yi ni Ọmọba Ọrun ti wọn tun n pe ni Àwé ba AWIKONKO sọrọ nipa iṣẹ to yan laayo. Ẹ ka ifọrọwerọ naa bo ṣe lọ.

Bi mo ṣe jẹ
Olufẹmi Ọrunṣọla lorukọ mi. nidi iṣẹ orin, awọn eeyan maa n pe mi ni Ọmọba-Ọrun, bẹẹ ni wọn tun n pe mi ni Àwé (ojo mi, mi o ba ẹnikẹni ṣe ọta, ẹni ejiri l’eji n pa).

Igba ti mo bẹrẹ iṣẹ orin kikọ
Ọjọ aboki temi naa ti pẹ nidi iṣẹ orin. Mo le sọ pe lati kekere ni mo ti n kọrin ninu ṣọọṣi, ṣugbọn nigba ti mo ṣawari ara mi pe mo ni ẹbun orin kikọ ati idaraya, ọdun 1999 ni. Ọdun 2001 ni mo ṣe awo orin akọkọ, to je alajumọṣe pẹlu awọn ẹlẹgbẹ mi nile ẹkọ giga, Igba Ọtun ni akọle ẹ. Lẹyin yẹn ni mo ṣe awo orin ti mo pe ni ‘Edumare don Bless Me’, eyi gan an lo gbe ogo mi jade sita. Lọdun 2014 ni mo tun gbe awo orin to gbẹyin jade, bo tilẹ jẹ pe mo tun ti n po awo orin min in pọ bayii, nitori pe mo ti n yọ ọ jade sita lẹyọ-kọọkan fawọn ololufẹ mi lati jẹgbadun ẹ.

Iṣẹ ti mo tun n ṣe yatọ si orin kikọ
Gẹgẹ bi ẹkọ ti mo kọ nileewe giga gbogboniṣe, iyẹn ẹkọ nipa eto ikansira-ẹni ati ibara-ẹni-sọrọ lori afẹfẹ (Mass Communication), mo n fi ṣiṣẹ oojọ nile ẹkọ giga gbogboniṣe tipinlẹ Ogun, iyẹn Moshood Abiola (MAPOLY) to wa niluu Abẹokuta. Igbagbo mi pombele ti mi o le ronupiwada ninu ẹ ni pe, ẹnikẹni ko ni nnkan ṣe lati pe ara ẹ ni olukọ nile ẹkọ gbogboniṣe ti kii b a a ṣe wipe ẹni naa n fi nnkan to n kọ awọn akẹkọọ si ojuṣe. Ile ẹkọ gbogbniṣe la pe e, o nii ṣe pẹlu pe keeyan maa fi nnkan to n kọ awọn eeyan nipa ẹ si ojuṣe. Ohun gan an lo tun n jẹ koriya fun wa nidi iṣẹ olukọ naa. ọpọlọpọ awọn ọga ta a ni naa ni wọn ṣe koriya fun, ti wọn tun n sọ fun wa pe ka maa ri daju pe a n fi ẹkọ ta a kọ awọn akẹkọọ wa si ojuṣe, eyi gan an lo jẹ didun inu mi lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi oṣere, onkọrin ati sọrọsọrọ ori redio pẹlu tẹlifiṣan. Awọn iṣẹ ti mo n ṣe yi ko tako ara wọn rara nitori pe akọni-mọn-ọn ṣe ni mo maa n pe ara mi. Ẹ lọọ wo Balogun (Coach) to ba a kọ eeyan ni bọọlu gbigba, oun naa gbọdọ le gba bọọlu sawọn. Ẹni to ba maa pe ara rẹ ni olukọ nile ẹkọ giga gbogboniṣe naa gbọdọ maa fi nnkan to n kọ awọn akẹkọọ si ojuṣe. Bi mo ṣe n ṣe ipolowo ori redio ati tẹlifiṣan (audio and visual jingles) naa ni mo tun n dawọn eeyan laraya lode ariya (MC). Iṣẹ ti Ọlọrun ko fi ran mi nikan ni mi o le ya sidi ẹ. A nilo lati ni awọn akẹkọ wọn a kẹkọọ, ti wọn a si le fi ẹkọ ti wọn kọ si ojuṣe, emi naa ṣi ni awọn ọga ti mo n tẹle, Afeez Oyetoro tawọn eeyan n pe ni Saka ati Baba Kafaya, olukọ lawọn naa nile ẹkọ giga, bẹẹ lemi naa tun lawọn ọmọ to n tẹle mi, bi ọrọ ile aye ṣe ri niyẹn. A gbọdọ maa da sawọn nnkan to n ṣẹlẹ lawujọ wa, yala eto oṣelu, ọrọ aje tabi eyikeyi. Ko digba ta a ba gba paali nileewe ka to maa wa ọna bi a ti maa lo o kaakiri, a ni lati bẹrẹ lati ile ẹkọ.

Image may contain: 7 people, people smiling, people standing, sky and outdoor
Nipa awo orin tuntun to n bọ lọna
Mo sọ fun yin pe mo ti n yọ diẹdiẹ sita ninu awo orin to n bọ lọna jade, eyi to ṣẹṣẹ jade ni mo pe ni ‘Ko Gba Gidigbo’ Gẹgẹ bi akoko oṣelu ta a wa yi, ohun ti mo ri daju ṣaka ni pe, ise ti awa oniroyin ati olorin le ṣe nipa bi alaafia yoo ṣe wa laarin ilu kii ṣe kekere, kosi ṣe e fọwọ rọ sẹyin, ọdun 2014 si 2015 ni mo gba imisi ẹ nigba ta a ṣeto idibo to kọja lọ, oyinbo si sọ pe ko si nnkan to dara bii ka ni agbekalẹ (idea) ti asiko ẹ ti de. Ti asiko nnkan ko ba tii to, asiko rẹ ko tii to niyẹn, ṣugbọn bo ṣe jẹ pe lati 2015 ni mo ti ko orin naa jọ, ọdun yi ni mo ṣẹṣẹ wa a gbe jade nitori pe o ba eto oṣelu to n lọ lọwọ mu. Ninu orin naa lati sọ fawọn eeyan pe ki wọn jẹ ka ṣe eto idibo ti ko nii ni kọnu-un-kọhọ ninu, ka ṣe eto idibo ti ko ba gidigbo de, ti kii ṣe pe ka maa fi ohun ija oloro le ara wa kaakiri nibi ipolongo, ati pe kawọn araalu ma jokoo sile. Eyi tawọn alakọwe gan an ṣe ninu ẹ lo pọ ju, nitori pe lọjọ idibo, kaka kiwọn jade dibo, ki wọn si pada sile, idi tẹlifiṣan ni wọn ma a wa lati wo fiimu. Awọn iṣẹ ti ko ṣe e ma jẹ ni mo jẹ fawọn ọmọ Naijiria ninu orin naa, ninu ẹ ni mo ti sọ pe ‘Ẹ maa y’ibo, ẹ maa j’ibo, ẹ jẹ ka dibo, ko gba gidigbo’. Nipele eto idibo ni mo ṣalaye sinu orin yii, ka si jade dibo fun ẹni ti ọkan wa ba yan, ta a ba dibo tan, ka duro ti ibo wa nitori pe ọjọ ọla wa la n daabo bo. Ọpọ ileeṣẹ redio ni wọn ti n lo orin naa. Fọnran, iyẹn fidio ẹ naa ko ni pẹ ẹ jade sita. Nigba ti eto idibo ba lọ bo ṣe yẹ, awọn oloṣelu gan an a ri aaye lati dari awọn araalu. Gbogbo awọn iṣẹ ta a ti ko jọ lati ọdun 2014 la fẹ ẹ gbe jade sita lẹẹkan ṣoṣo.

Amọran mi fawọn to fẹ maa kọrin
Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju, nnkan to le mu kiru awa yi maa kọrin, o tunmọ si pe a fẹẹ jẹ awokọṣe fawọn ọdọ. Ọpọ awọn ọdọ ni wọn gbagbọ pe bi wọn ko ba kọrin takasufe, paapaa ikọkukọ, iyẹn awọn orin ti ko tọna lori afẹfẹ, wọn ko le tayọ. Nigba tawa n dagba, awọn orin Ebenezer Obey, Sunny Ade atawọn orin to jẹ orin iwuri la n gbọ nigba naa. Olorin to n kọrin lati tun awujọ ṣe (lifestyle) ni mo jẹ, nitori naa mo fẹ kawọn ọdọ mọ pe iṣẹ orin kikọ kii ṣepe nitori wọn fẹẹ fi di olowo ojiji. Wọn gbọdọ ri i pe inu wọn n dun si orin ti wọn n kọ, wọn gbọdọ rii gẹgẹ bi nnkan to n mu inu wọn dun, ti wọn ba rii bẹẹ, nigba ti asiko ba to, owo lo maa wa wọn wa funra ẹ, kii ṣe iṣẹ orin nikan, gbogbo iṣẹ ni. A ni lati ni suuru daadaa, ka ma sare kanju wa owo, nitori pe kii ṣe ọjọ taa ba bimọ lo maa rin.

Image may contain: one or more people and text 
Afojusun mi lọdun mẹwaa si asiko yi
Pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun, mo gbagbọ wi pe ka to o tun pada dibo min in lọdun 2023, laarin awujọ olorin nilẹ Naijiria, emi naa a ti laami-laaka ju bi mo ṣe wa bayii lọ, ati pe bi Ọlọrun ba ran mi lọwọ, mo fẹẹ da ileewe temi silẹ, nitori pe pupọ ninu awọn ta a wo niwaju, ti wọn ṣiṣẹ wọn ni aṣe ye, ni wọn ko lanfaani lati fa awọn eeyan lọwọ soke, wọn raaye lati jẹ awokọṣe fawọn min in. Mo fẹẹ jẹ eeyan alaṣeyọri, ati pe aṣeyọri ẹda ko tii pe bi ko ba fa eeyan kan lọwọ soke. Ẹ wo Oloogbe Gbega Adeboye nigba aye ẹ, sọrọsọrọ to laami-laaka ni, ẹ wo ọdun to ti ku, ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi n sọrọ nipa ẹ. Awọn sọrọsọrọ kan ti sọ Gbenga Adeboye di oriṣa ti wọn n bọ lọdọọdun. Mo fẹẹri ara gẹgẹ bi ẹni to maa fi orin tun igbesi aye eeyan ṣe, paapaa orileede Naijiria.

Nipa aṣọ funfun ati alawọ ewe ti mo maa n wọ
Gbogbo iṣẹda patapata nile aye yi, paapaa lawujọ ewe, ẹyẹ ati ẹranko ni wọn ni ohun idanimọ wọn. Anọmọ ni ti Ọga, ṣugbọn gẹgẹ bi ifẹ ti mo ni silẹ wa Naijiria lapa kan, ati iran ti mo ri, aawọ funfun ati ewe jẹ eyi to maa n ṣi imisi silẹ fun mi. Igba min in wa to jẹ pe ti mo ba ni irẹwẹsi ọkan, mo maa n lọ sinu ọgba ewe, paapaa nibi ti ododo ba wa, ma a lọ maa bawọn sọrọ. Ti a ba ti n sọrọ, gbogbo nnkan to ba n dami laamu, ni wọn maa n sọ imisi kalẹ fun mi, idi ni yii ti mo fi maa fẹran aawọ yẹn, nnkan to tun fi jẹ iwuri fun mi ni pe, o jẹ aawọ orileede wa Naijiria. Ileeṣẹ mi ti mo forukọ rẹ silẹ labẹ ofin, Papa-Oko-Tutu (Green Pastures) lorukọ ẹ. Aami idanimọ mi niyẹn, nitori pe o ba iṣẹda mi lọ. Aranṣọ ni mama mi ko too ku, awọn gan an ni wọn foju sọna oge ṣiṣe bii ka wọ aṣọ danṣiki, kẹmbẹ abbl, mo tun fi maa n mu inu mama mi lọrun dun ni. Mi o ṣe awo rara, ṣugbọn idi to fa a ni mo sọ fun un yin yẹn, mi  o si ninu ẹgbẹkẹgbẹ kankan.

Ni ti awọn eweko ti mo n ba sọrọ
Ṣe ẹ ri gbogbo nnkan to wa laye patapata ni wọn ni eti, awọn oniṣẹṣe maa n pe ilẹ, ilẹ si n da wọn lohun, wọn tun maa n ni ẹni to ba dalẹ a ba ilẹ lọ. Emi gẹgẹ bi ẹnikan, mo jẹ ẹni ta a le pe ni onimisi, nilana Musulumi, wọn a ni Aafa, ni ti Kristẹni, wọn pe e ni Wolii, ṣugbọn emi nigbagbọ ninu iṣẹda gidigidi. Awon eweko n ba wa sọrọ, fun awọn to ba ni eti ni, gbogbo nnkan to si yi wa ka ni Ọlọrun fi n ba awa ẹda eeyan sọrọ, ṣugbọn ọpọlọpọ wa ni a ko ṣi eti inu ati oju inu wa silẹ mọ. Ti ẹ ba ri ẹni to ni iporuru ọkan, to ba bọ si ẹgbẹ odo, to n wo bi omi yẹn ṣe n lọ, o wa lara nnkan to le mu ki ọkan eeyan tutu. Nigba ta a wa ni kekere, ti a ba n ṣere oṣupa, kii ṣe ere ta a n ṣe yẹn la n gbadun, ṣugbọn imisi to n jabọ le wa lori labẹ oṣupa yẹn lo n jẹ ẹkọ fun wa. Bo tilẹ jẹ pe mo ṣi n ṣe iwadii si i, mo mọ daju pe gbogbo nnkan patapata lo ni eti ti wọn fi n gbonran, awọn kan n gbọ ju awọn kan lọ, ọlaju lo si ko wọn kuro lawujọ wa, ki Ọlọrun ko ran wa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI