AGABANGEBE LO N DA GOMINA AMOSUN ATI ẸGBẸ OṢELU APC LAAMU - JITI OGUNYẸ JU BỌNBU ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 6, 2019

AGABANGEBE LO N DA GOMINA AMOSUN ATI ẸGBẸ OṢELU APC LAAMU - JITI OGUNYẸ JU BỌNBU ỌRỌ

"Koda, ẹgbẹ oṣelu kan o baa jẹ Ajinigbe Party of Nigeria, niwọn igba to ba ti le gbe wọn de ipo ti wọn n wa. wọn yoo dara pọ mọ ọ".

Laipẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu APC paṣẹ lọ rọọkun ile fun Gomina Ibikunle Amosun ti ipinlẹ Ogun latari pe ẹgbẹ ni o n ṣe lodi si ofin ẹgbẹ nipa atilẹyin rẹ fun oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu min in, Ọnọrebu Abdulkabir Akinlade.

Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa lo daba yii lẹyin ipade wọn to waye nilu Abuja.

Ẹwẹ, onimọ nipa ofin kan, Jiti Ogunyẹ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ laipẹ yi ṣalaye pe pupọ ninu igbesẹ awọn ẹgbẹ oṣelu lorilẹede Naijiria mọ ohun ti wọn n ṣe.

Lotitọ igbesẹ gomina Amosun yoo jẹ ki awọn ẹgbẹ mọ pe ṣekuṣẹyẹ ni iwa to wu, to si lodi si ofin ẹgbẹ wọn.

O jẹ ko di mimọ wi pe olori ọrọ inu rẹ ni wi pe ohun ti ẹgbẹ ba ṣe naa lawọn araalu yoo gba.

"Niwọn igba to jẹ pe ẹgbẹ APC naa lo fun un ni aaye lati dije fun ipo Sẹnetọ, ki lo de to jẹ pe igba ti wọn dibo tan ni wọn to mọ pe awọn ko fara mọ ohun ti Amosun n ṣe?"

O ni agabagebe ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ti wọn fi ni ki Gomina Amosun lọ rọọkun ile.

Amoṣa, Amofin Jiti jẹ ko di mimọ pe niwọn ti ko jẹ tuntun pe awọn oloṣelu n ṣi kuro lati ẹgbẹ kan lọ si omiran, "ti a ba ba akata wi pe o lọ jẹ laatan, o yẹ ki a ba adiyẹ naa wi".

Nitori naa, o ni ohun ti Amosun naa n ṣe ku diẹ kaato nitori ipo lawọn oloṣelu n wa kaakiri. Ohun ti Amosun ṣe, awọn gomina min in naa ti ṣe e nipinlẹ min in.

O ran awọn araalu leti wi pe o le da bii wi pe awọn oloṣelu n ja loju araalu ṣugbọn bo ba di ọla, wọn yoo di ọrẹ ti wọn a maa rẹrin kaa kaa.

Latari ohun ti yoo bi ni saa Amosun gẹgẹ bii Sẹnetọ labẹ asia APC, Jiti ni ọrọ oloṣelu ko ṣee da si taara nigba mii nitori bi idibo ti gomina yii ba ti pari ti wọn bura wọle fun un gẹgẹ bii sẹnetọ, fun apẹẹrẹ bi oludije aayo rẹ ko ba pegede, o le tun pinu lati pada si APC ti ẹgbẹ APC naa a si tun fọwọ paa lori.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI