AṢIRI IKU TO PA ILU VENTURE, GBAJUMỌ OṢERE TIATA RE O, ATI BI WỌN ṢE SIN IN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 7, 2019

AṢIRI IKU TO PA ILU VENTURE, GBAJUMỌ OṢERE TIATA RE O, ATI BI WỌN ṢE SIN IN

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta 

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi iroyin lo ti jade sori ayelujara latari iku gbajumọ oṣere tiata nni, Oloye Alfred Rotimi Popoọla, ṣugbọn ti AWIKONKO ti pada ṣewadi naa daadaa.

Ṣe ni ariwo ibanujẹ nla tun sọ lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba ti ọkan lara awọn agba ọjẹ nidi iṣẹ tiata ti TAMPAN nipinlẹ Ogun, Oloye Alfred Rotimi Popoọla dagbere faye laarọ ọjọ Wẹside ọsẹ to kọja yi.

Bawọn kan ṣe n sọ pe iku gbajumọ oṣere tiata naa kii ṣoju lasan, o lọwọ aye ninu, bẹẹ lawọn kan n sọ pe amuwa Ọlọrun ni, tawọn min in si n sọ pe akufa to n ṣẹlẹ lagbo oṣere tiata lo fa a.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni lati bi ọsẹ mẹta sẹyin ni Alfred tọpọ awọn eeyan tun n pe ni Ilu Venture fi ẹsẹ kọ, ti ẹsẹ naa ko si jẹ ko gbadun latigba naa, eyi ti wọn loo da a jokoo sile, ti ko le jade lọ sibi kankan.

Ẹsẹ naa la gbọ pe o ba a ja titi ti ko fi yọju sibi ipade tẹgbẹ osere TAMPAN ṣe, paapaa nibi ti wọn ti gbe ọpa aṣẹ fawọn oloye tuntun niluu Abẹokuta, eyi to waye lọjọ kọkanlelogun oṣu keji to kọja yi.

Nigba to maa ku, a gbọ pe ẹsẹ naa ni won lo o sọ pe o n dun oun gidi, ko si pẹ ni wọn loo tun bẹrẹ sii sọ pe ori n fọ oun, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu adani kan ladugbo to n gbe ni Ibẹrẹkodo, nijọba ibilẹ Abẹokuta North, iyẹn lọjọ Mọnde ọsẹ to kọja yi.

AWIKONKO gbọ pe nigba to maa di aarọ Tuside ni wọn loo bẹrẹ sii sunkun pe ori to n fọ oun naa ti kọja sisọ, eyi lo mu ki wọn tun sare gbe e lọ si FMC lati tọju ẹ, bi wọn ṣe gbe e de bẹ ni wọn ti bẹrẹ sii tọju ẹ.

Ohun ta a tun gbọ ni pe nigba to maa di ọwọ irọlẹ, ṣe lọrọ naa tun yiwọ ni ọsibitu FMC to wa ladugbo Idi-Aba, to muu ki wọn gbe ẹrọ afẹfẹ igbalode (oxygen) sii nimu nitori to ti wọ kọma (coma).

Eyi ni wọn ṣe titi to fi di aarọ kutu ọjọ Wẹside to dagbere pe o digboṣe. Ere ni wọn kọkọ pe e, afigba ti wọn lawọn nọọsi tare oku ẹ si mọṣuari pe ẹmi ti kuro lara ẹ, lo mu kariwo sọ.

Ẹsẹ ko gbero lọsibitu FMC lọjọ naa biroyin naa ṣe tan sita, ko da a ti wọn lawọn alaṣẹ ọsibitu naa paṣẹ fawọn sikiọriti ẹnu geeti pe ẹnikẹni ko gbọdọ wọle mọ, ṣugbọn ti wọn pada ṣii nitori awọn ti wọn waa gba itọju nibẹ.

Lẹsẹkẹsẹ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ ipalẹmọ isinku ẹ, eyi ti wọn ṣe ni ṣọọṣi to n lọ, iyẹn St Jude Cathedral to wa ladugbo Ibẹrẹkodo nibẹ. Ẹsẹ ko gbero ninu ṣọọṣi naa nigba ti wọn n ṣe ẹyẹ ikẹyin fun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Oloye Ṣeyi Crown to ṣalaye bi gbogbo nnkan naa ṣe lọ jẹ ko di mimọ pe gbogbo eto ati ẹyẹ ikẹyin to yẹ ki ẹgbẹ oṣere TAMPAN ṣe lawọn ti ṣe fun un lọjọ Tọside ti wọn si n naa, ati pe awọn lawọn lọọ gbe oku ẹ ni mọṣuari.


“Ẹsẹ kekere kan lo fi rọ, a ṣe inauguration TAMPAN lọjọ kọkanlelogun oṣu to kọja yi, igba ti a ko rii la fi pe e lati beere idi ti ko fi yọju, ko to wa a ṣalaye pe ẹsẹ kan toun fi rọ lo n ba oun ja, toun ko le jade. Lọjọ idibo apapọ to kọja lọ, o wa ladugbo ẹ, nitori pe oun ni adari ẹgbẹ oṣelu ADC ladugbo ẹ.

“Nigba to tun di ọjọ Mọnde lo sọ pe ori kan n fọ oun, tawọn ẹbi ẹ si gbe e lọ si ọsibitu kan ladugbo wọn nibi ti wọn da a duro sii. Aarọ Tuside lo tun sọ pe ori naa ti kọja nnkan ti wọn le tọju nibẹ, eyi lo mu ki dọkita ọsibitu naa sọ pe ki wọn maa gbe e lọ si FMC.

“Igba igba to maa to irọlẹ lo wọ kọma, ni wọn gbe ẹrọ afẹfẹ igbalode, iyẹn oxygen si i nimu, nigba to maa di aarọ Wẹside lo dake. Gbogbo eto to yẹ ka ṣe fun un la ti ṣe. Mi o nigbagbọ pe eeyan lo pa a, to ba si jẹ eeyan lo wa nidi ẹ, o ku ẹni naa pẹlu Ọlọrun.”

Bo tilẹ jẹ pe a ko mọ iye iyawo ati ọmọ ti Oloogbe naa fi silẹ lọ, ṣugbọn AWIKONKO gbọ pe iyawo ẹ mẹta atawọn ọmọ ni wọn wa nibi isinku lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI