EYI NI BI ABIỌDUN, SANWO-OLU, MAKINDE ATI ABDULRAZAQ ṢE JAWE OLUBORI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 11, 2019

EYI NI BI ABIỌDUN, SANWO-OLU, MAKINDE ATI ABDULRAZAQ ṢE JAWE OLUBORI

PDP jáwe olúbori ni ìpínlẹ̀ Oyo, APC ni Kwara, Ogun àti Eko

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ló jáwe olúbori ní ìpínlẹ Kwara, Ogun àti Eko nígbà ti ọmọ ẹgbẹ́ People's Democratic Party gbégba orókè ni ìpínlẹ̀ Oyo.

Seyi Makinde ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fẹ̀yìn Adebayo Adelabu APC janlẹ̀ pẹ̀lú ìbò 515,621 si 357,982

nígbà ti Dapo Abiodun ẹgbẹ́ òṣèlú fẹ̀yìn Adekunle Akinlade ẹgbẹ́ APM jàlẹ̀ pllú ìbò 241,670 sí 222, 153 ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Jimi Agbaje ẹgbẹ́ òsèlú PDP fìdírẹmi nípinlẹ̀ Eko nígbà ti Babajide Sanwo-Olu ẹgbk òṣeelú APC fi ìbò 739,445 si 206,141 jáa jù sílẹ̀.

Ní ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrahman Abdulrazaq ti APC fìdíi Abdullrazaq Atunwa ti ẹgbẹ òṣèlú PDP rẹmi pẹ̀lú ìbò 331546 si 114754.

Seyi Makinde ló jáwé olúborí ni ìpínlẹ̀ Oyo
Seyi Makinde tó jẹ olùdíje lábẹ́ òṣèlú People's Democratic Party ló jáwé olúbori níbi ìdìbò gómìnà tó wáye ọ́jọ́ sátide.

Makinde ni ìbò 515,621 nígbà ti akẹgbẹ́gbẹ́ rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress Adebayo Adelabu ni 357,982.

Ta ni Babajide Sanwo Olu gomina tuntun Eko ti INEC kéde?
Àwọn ohun tí o lè má mọ̀ nípa Babajide Sanwoolu, tó jáwé olubori nidibo gomina Eko.

INEC kéde Babatunde Sanwo Olu APC pé ó fẹyin Jinmi Agbaje ti PDP atawọn tó kù janlé ninu idibo ọjọ Abamẹta.

INEC kéde Sanwo-Olu ti APC gẹ́gẹ́ bí gomina tí wọn dìbò yàn nípínlẹ̀ Eko
Ajo INEC ni ipinlẹ Eko ti kede Olajide Sanwo-olu gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oselu APC to jawe olubori pelu ibo 739,141, nigba ti Jimi Agbaje ti ẹgbẹ oselu PDP ni 206,14.

APC jáwé olúborí ẹkùn ìdìbò 21 nínú 25 nípínlẹ̀ Kogi
Ajo INEC nipinlẹ Kogi ti ni ẹgbẹ oselu APC ti bori ninu gbogbo esi idibo mọkanlelogun ti wọn si kede rẹ ninu mẹẹdọgbọn.

Ẹgbẹ oselu PDP ko yege ni agbegbe kankan ninu eleyii ti wọn ti i ka.

Awọn agbeegbe ti wọn ko ka naa ni wọn ti sọ wi pe idibo ko fẹnuko nibẹ. Awọn agbeegbe naa ni Lokoja 1, Igalamela, Odolu LGA ati Omala.

O tun fikun wi pe gbogbo awọn osisẹ Ajo INEC ti wọn jigbe ni Ọjọ Isinmi ni wọn ti gba pada gẹgẹ bi ọrọ ti agbẹnusọ ajọ INEC Ahmed Bagudu sọ.

Jimi Agbaje kí Sanwo-Olu kú oríire
Oludije lẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Eko, Olujimi Agbaje ti ki oludije lẹgbẹ oselu APC, Sanwo-Olu ku oriire.

Iroyin ni pe Agbaje pe Sanwo-Olu lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ lati kii ku oriiirẹ lẹyin idibo sipo gomina ipinlẹ Eko.

Amọ, Ajọ INEC ko i tii kede Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oselu APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI