O TAN: FAYỌṢE YẸYẸ GOMINA AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 11, 2019

O TAN: FAYỌṢE YẸYẸ GOMINA AMOSUN

Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Oloye Ayọdele Fayọṣe ti gba ori ẹka ayelujara rẹ, ti twitter lọ lalẹ ana lati fi gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ṣẹlẹya latari bi ọmọ oye ẹ, Ọnọrebu Adekunle Akinlade ṣe padanu nbi idibo gomina to kọja lọ yi, ti ajọ INEC kede Ọmọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

Gomina Fayọṣe lasiko to n kọ ọrọ naa sọ pe iwe ‘otoge’ni wọn ja fun Gomina Amosun to lewaju lati gba ijọba ipinlẹ Ekiti lọwọ oun fun ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to kọja.

Ninu ọrọ ẹ, o sọ pe “Mo ki Gomina Ibikunle Amosun ku oriire pe o padanu idibo gomina ti ọmọ oye ẹ, Adekunle Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM.

“Oun naa ti wa a le darapọ mọ ẹgbẹ wa, lẹyin to ti fi tipa ṣagbatẹru bi wọn ṣe yi ibo ipinlẹ Ekiti lọdun 2018 pẹlu Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji yi kan naa to jẹ aṣoju ọga INEC fun eto idibo nipinlẹ mejeeji.

“ YE Ibikunle Amosun, jọwọ darapọ mọ wa bi a ti n ja ijangbara ipadanu wa nile ẹjọ Tribunal. Laala to lọ soke, ilẹ lo n padabọ. Ohun to ba lọ, yoo tun pada wa a ni. Iwọ ja Ekiti gba, wọn ja Ogun gba lọwọ ẹ.
“YE, jọwọ ma ṣe gbagbe lati ki Ọlọlajulọ Dapọ Abiọdun ku oriire o.

Orukọ mi ni Ayọ Fayọṣe.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI