SIR KESSINGTON ADEBUTU MU LADI ADEBUTU LỌỌ BẸ DAPỌ ABIỌDUN L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 18, 2019

SIR KESSINGTON ADEBUTU MU LADI ADEBUTU LỌỌ BẸ DAPỌ ABIỌDUN L'EKOO

 Latigba ti Oludije sipo Gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti jawe olubori ni wọn lọkan Ọnọrebu Oladipupọ Adebutu, LADO ko ti balẹ molatari bo ṣe kẹyin si Abiọdun ti wọn jọọ jẹ ọmọ agbegbe kan naa.
Ninu idibo awọn Gomina to kọja yi, ko seni ti ko mọ pe Ọnọrebu Adekunle Akinlade, iyẹn Triple A ti Gomina Ibikunle Amosun fa kalẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM lo tẹle.
Nnkan ti wọn loo ṣakoba fun Ọnọrebu Adebutu ni iwe adehun toun ati Ọnọrebu Akinlade bu owo lu pe gbogbo nnkan ti yoo gba lati ríi pe Omoba Dapọ Abiọdun ko wọle loun yoo ṣe, ti wọn si tun gbe iwe adehun naa sita fawon eeyan lati ri.
Oludije sipo Gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP tile ẹjọ ko f'ọwọ si ni Ọnọrebu Adebutu, eyi gan an ni wọn loo jẹ ko pada sẹyin pe oun ko du ipo naa mọ, ati pe oun ti gba lati ṣiṣẹ fun Ọnọrebu Akinlade, nigba ti idibo naa ku ọjọ meji pere.
Ọpọ awọn araalu ni wọn bu ẹnu atẹ lu Ọnọrebu Adebutu lori iwa to hu, ati pe nitori owo lo ṣe fi oṣelu ẹtanu tako Ọmọba Dapọ Abiọdun ti wọn jọọ jẹ ọmọ Ipẹru, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC nikan lawon eeyan dibo niluu Ipẹru, to fi mo wọọdu ti Ọnọrebu Adebutu funra rẹ ti dibo.
AWIKONKO gbọ pe latigba ti ajọ INEC ti kede Ọmọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ni wọn ni ọkan Ladi Adebutu ko ti balẹ mọ, ko da, ti wọn sọ pe ko le rin bo ṣe n rin tẹlẹ niluu Ipẹru mo latari itiju, ti wọn si tun lawon kan n buu bi wọn ba foju kan an.
Itiju yi ni wọn loo mu ki LADO maa bẹ baba ẹ pe ko ba oun bẹ Ọmọba Dapọ Abiọdun, ati pe ko je k'awọn maa ṣe bi tẹgbọn taburo.

Laarọ onii Mọnde ni Sir Adebutu Kessington, iyẹn Baba Ijẹbu to jẹ Baba LADO muu lọ ọ bẹ Dapọ Abiọdun niluu Eko, nitori ohun ta a gbọ ni pe o ṣee ṣe k'awọn to n binu si LADO ma jẹ ki ipade naa yọri si rere bi wọn ba ṣee nile Dapọ to wa ni Ipẹru



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI