Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọpọ awọn ololufẹ gbajumọ sọrọsọrọ nni, Ọgbẹni Ibrahim Kehinde Garuba ni wọn ti n reti pe ki aago mọkanla kọja isẹju mẹẹdogun tete lu, k'awọn le jẹ'gbadun eto tuntun to fẹẹ bẹrẹ ni ẹka ileeṣẹ redio ijọba apapọ, iyẹn Paramount 94.5FM.
Kehinde, ọmọ bibi ilu Ọyọ t'awọn eeyan tun mọ si Van Garuba la gbọ pe lẹyin ipade pẹlu awọn alakoso ileeṣẹ redio naa lọsẹ meloo kan sẹyin ni wọn ti fẹnu ko pe yoo maa lo iṣẹju marundinlaadọta (45minutes) lati fi dawọn eeyan laraya.
AWIKONKO gbọ pe gbogbo ọjọ Wẹside, bẹrẹ lati aago mọkanla kọja isẹju mẹẹdogun ni eto to pe ni 'O N ṢẸLẸ' naa yoo maa waye titi di aago mejila ọsan (11:15AM - 12noon).
Oriṣiriṣi abala ni eto naa pin si, fawọn araalu lati jẹ igbadun eto agbọfikọgbọn naa.
Fawọn to ba mọ gbajumọ sọrọsọrọ naa daadaa, wọn yoo mọ pe ogbontarigi to mọ nnkan to n ṣe ni okunrin ti wọn n pe Van Garuba yi.
Van Garuba ti ṣeto lawọn ileeṣẹ redio bii OGBC ati Family at'awọn redio min in kaakiri.
No comments:
Post a Comment