ILE ẸJỌ N FI AWỌN ỌTẸLẸMUYẸ WA DASUKI KAAKIRI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 16, 2019

ILE ẸJỌ N FI AWỌN ỌTẸLẸMUYẸ WA DASUKI KAAKIRI O

Ile ẹjọ giga FCT to fikalẹ sagbegbe Maitama niluu Abuja lonii Tuside ti paṣẹ pe afi kawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iṣẹ tọsan-toru lati ri i pe Oludamọnran lori ọrọ eto aabo lorileede Naijiria tẹlẹ, Ọgbẹni Sambo Dasuki de ile ẹjọ lati wa a sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, eyi to n jẹ lọwọ.
 
Nigba to n gbe iwe aṣẹ naa le ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ, iyẹn DSS lọwọ nile ẹjọ lonii, Onidajọ Husseini Baba-Yusuf sọ pe dandan ki ọkunrin naa yọju lati wa a sọrọ lori ẹjọ to n jẹ lọwọ, di po ko ma a fa idiwọ fun igbeṣẹ ile ẹjọ.

Bẹ o ba gbagbe, lara ẹsun ti wọn fi kan Dasuki ni pe o ṣe owo eto aabo kumọ-kumọ, bẹẹ lo si tun da alaafia orileede Naijiria laamu. Dasuki pẹlu ọga agba ajọ NNPC tẹlẹ, Aminu Baba Kusa, Acacia Holdings ati Reliance Referral Hospital lawọn tọrọ naa tun kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI