NITORI ỌGINNI TO N F'ORUKỌ ẸGBẸ OṢELU LABOUR LU JIBITI, ARABAMBI SỌKO ỌRỌ SI ṢẸGUN ỌṢỌBA ATI DAPỌ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 1, 2019

NITORI ỌGINNI TO N F'ORUKỌ ẸGBẸ OṢELU LABOUR LU JIBITI, ARABAMBI SỌKO ỌRỌ SI ṢẸGUN ỌṢỌBA ATI DAPỌ ABIỌDUN

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayọmi Arabambi ti pariwo sita pe afi ki Gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ati Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọba Dapọ Abiọdun tete gbe igbese lati sa fun Ọgbẹni Ọginni Ọlapọsi to n f'orukọ egẹg oṣelu Labour lu awọn eeyan ni jibiti, bi bẹẹ kọ, wọn yoo kan abuku nile ẹjọ

Lonii ni Kọmureedi Arabambi to tun jj alaga fun gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ naa, iyẹn Intra-Party Advisary Council, IPAC sọrọ naa lasiko to n b’AWIKONKO sọrọ lẹyin ti wow kuro nile ẹjọ Tribunal ti ọkunrin naa, Ọginni gbe ẹjọ kan lọ lorukọ oludije sipo Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour.

Arabambi sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe ẹni to pe ejẹ gan an ko yọju si kọọtu nitori to mọ pe ẹjọ ti ko l'ẹsẹ nilẹ lo f'orukọ ẹgbẹ oṣelu Labour pe, ati pe oludije sipo Gomina, Oloye Arabinrin Modupẹọla Sanyaolu to pe ejo lorukọ ẹ gan an ko mọ nnkankan nipa ẹjọ to pe.

O loo ya oun lẹnu pe lasiko ti igbẹjọ naa n ll lọwọ, ile Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ni Ọginni wa, to lọọ ba a ṣe ọtẹ pẹlu Ayọ Olubori, toun ko si mọ nnkan ti ipade naa da lori, fun idi eyi, o ni ki Oloye Ọṣọba ati Ọmọba Dapọ Abiọdun le ọkunrin naa jinna, ko ma baa ba wow lorukọ jẹ loju gbogbo aye.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “O ya wa lẹnu pe ọsẹ to kọja lawọn kan pe ejo pe wọn yọ orukọ Gomina awọn kuro ninu iwe idibo, igba taa maa wo, a ṣakiyesi pe Gomina ẹgbẹ wa ni wọn n sọ. Awuyewuye naa lo gbe wa de ile ejo lati so fun ile ejo pe awa ko mo won ri rara, won kii se omo egbe wa.

“Gomina ti mo yan lojo kerin osu kesan, Arabinrin Sanyaolu ni won pe ni Gomina awon, o je kayeefi fun mi. Inu mi si dun pe ile ejo gan an je ko ye gbogbo awa ta a wa nibe lonii pe ejo won ko lese nile. Nigba ti ejo naa n lo lowo, sa dede la ri foto ti Oginni gbe sita, eyi to ya pelu Oloye Segun Osoba ati Onorebu Ayo Olubori to je Komisana Gomina Amosun, nibi ipade ti won se lasiko ti ejo n lo lowo.

“Bawo ni eni to n pe ara re lomo egbe oselu Labour tun se maa lo sepade pelu egbe oselu min in lasiko ti ejo to pe n lo lowo. Iru awon eeyan bi Oginni ko lo ye ka maa ri pelu Baba Osoba to loruko, to si ni iyi lawujo, a si bowo fun won gidi gan an laarin ilu. Nitori naa, ko ye ki Baba Osoba je ki Oginni ta epo si aso aala e.

“Idi ipade ati foto ti won ya yen gan an ko tii ye wa, boya emi mi gan an wa ninu ewu bayii, mi o le so. Sugbon sa, mo dupe pe ile ejo pase pe ejo won ko lese nile, nitori pe eni to gbe ejo wa ko letoo labe ofin lati pe iru ejo bee.”

Nipa ti bi ajo INEC se yo oruko egbe oselu Labour kuro ninu iwe idibo, Arabambi so pe “Inui we ofin orileede yi ni ireti wa wa. Iwe ofin je ko ye wa biru nnkan bayi ba sele pe bi ona meji lo pin si, okan wa lowo egbe oselu, ekeji wa lowo INEC, tiwa ni lati fi eri han fun ile ejo. Gbogbo nnkan to ye lati se, igbese to ye ka gbe lati gbe, eyi tawon to n foruko wa lu jibiti ko nii.

“Bi mo se n baa yin soro yi, mi o ni pada seyin lori ejo ejo, nitori pe awuyewuye to n lo nip e Arabambi fee fi pawo ni, to si je abuku fun mi. Mo si mo pe dandan ni ka tune to idibo yi di. Bo ba wu Oloye Segun Osoba ati Dapo Abiodun, wọn le jokoo ipade pọ pẹlu Ọgbẹni Ọginni laimọye igba, ko le mi wa, nitori pe idajọ ododo la n wa. Dandan ni ki ajọ INEC tun idibo naa di bi ile ẹjọ ba da wa lare, ti mo si nigbagbo pe idalare ni ti wa.

Nigba toun naa n b’AWIKONKO soro, Oludije sipo Gomina labe egbe oselu Labour naa so pe “Iyalenu lo je fun mi nigba ti mo gbo pe awon kan ti mi o mo rii rara, ti a ko jo duro soro ri pe ejo loruko mi, ti won si n ba mi loju je kaakiri pe mo gbe ajo INEC lo sile ejo, ati pe egbe oselu Labour kan soso lo wa ti mo mo, to si je pe Komureedi Arabambi ni alaga e nipinle Ogun.

“Looto, ko ye mi bi won se yo oruko mi kuro ninu iwe idibo, mi o le so boya awon kan ni won sagbateru e, sugbon nnkan ti mo mo ni pe ajo INEC gbodo dahun fun nile ejo, eyi ti alaga mi to je ojulowo ti gbe igbese.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI