O MA ṢE O; AGUNBANIRỌ KU LẸYIN ỌJỌ KẸTA TO ṢEGBEYAWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 29, 2019

O MA ṢE O; AGUNBANIRỌ KU LẸYIN ỌJỌ KẸTA TO ṢEGBEYAWO

Bawọn kan ṣse n sọ pe ọrọ naa kii ṣoju lasan, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o lọwọ aye ninu, tawọn kan si n sọ pe ayanmọ Ọlọrun ni, latari bi agunbanirọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ferdinand Lorwuese Kutar, eyi ti wọn loo ku lẹyin ọjọ kẹta to ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ ẹ, iyẹn lọsẹ to kọja yi.

Corps member dies mysteriouslyBawọn mọlẹbi oloogbe naa ṣe n gbera ṣanlẹ, bẹẹ lawọn kan n wa ẹkun mu, tawọn kan si barajẹ pupọ lọjọ Satide Abamẹta, ijẹta to kọja yi nibi ti wọn ti n fi eeru fun eeru, erupẹ fun erupẹ niluu ẹ, Tse Kutar Nyiev, to wa nijọba ibilẹ Guma ipinlẹ Benue.

 
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kẹtala oṣu yi ni Kutar ṣegbeyawo ibilẹ pẹlu ololufẹ ẹ, to si jẹ pe kayeefi niku ẹ jẹ lọjọ kẹrindinlogun to jẹ ọjọ kẹta igbeyawọ to ṣe. Ipinlẹ Zamfara la gbọ pe oloogbe naa ti n sin orileede baba ẹ lọwọ.
Corps member dies mysteriously

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI