REBECCA TI ỌRẸKUNRIN RẸ JA JU SILẸ GBE MAJELE JẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 19, 2019

REBECCA TI ỌRẸKUNRIN RẸ JA JU SILẸ GBE MAJELE JẸ

Iyalẹnu lọrọ ọdọmọbinrin kan tọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun mejilelogun lọ, Rebecca Michael ṣi jẹ fawọn eeyan paapaa awọn to suynmọ latari bo ṣe gbe oogun ekute jẹ lojiji, o si gbabẹ sọda sọrun alakeji, lọjọ Wẹside ijẹta yi.

Ohun ta a gbọ pe o fa sababi bi Rebecca ṣe pinu lati gbe majele jẹ ni bi wọn ṣe sọ pe ọrẹkunrin ti wọn jọ n fẹ ara wọn ṣe ja a ju silẹ, to si ba ẹlomin in lọ.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo igbiyanju Rebecca lati jẹ ji ọrẹkunrin rẹ ti wọn loo yan iṣẹ DJ laayo yi gba ti ẹ pada, ki wọn si maa ba ifẹ wọn lọ bii ti tẹlẹ lo ja si pabo, to si wo o pe kaka kilẹ ku, oun yoo yamọ gbẹmi ara oun ni.

Awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe Rebecca ṣẹṣẹ wọ ile iwe giga fasiti tipinlẹ Kogi ni, iyẹn Kogi State University to wa ni Ayingba, Lọkọja.

A ti ẹ gbọ pe ko pẹ ti Rebecca gbe oogun ekute naa jẹ lawọn eeyan ri nibi to ti n japoro nilẹ, to si mu ki wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu ijọba apapọ, FMC to wa nitosi, ṣugbọn ti wọn ni ẹpa ko boro mọ nigba ti wọn yoo fi debẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI